Tani ọ̀jọ̀gbọ́n Marius Iwuchukwu tó ṣéése kí òun àti ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ pa ara wọn ní US?

Aworan

Oríṣun àwòrán, Duquesne Catholic University

Ọjọgbọn Marinus Iwuchukwu lati Naijiria to jẹ olukọ nipa imọ ẹsin lagbaye ni wọn ti ba oku rẹ ati ti ọrẹbinrin rẹ, Charce Dun ni orilẹede Amẹrika.

Awọn mejeeji ni wọn ba oku wọn ni agbegbe Thorncrest Drive, Wilkins Township, ni ilu Pittsburg lẹyin ti awọn kan ta wọn ni olobo pe awọn kan n ja ninu ile.

Ileeṣẹ ọlọpaa Allegheny County ni awọn gba ipe pe ki wọn pe ile awọn tọkọ-taya naa ninu ile lati mọ ohun to n ṣẹlẹ nibẹ.

''O ṣeeṣe ki wọn gun ara wọn lọbẹ, ki ekeji si pa ara rẹ''

Gẹgẹ bi awọn to ta wọn lolobo ṣe sọ, ara adugbo wọn lo pe pe wọn ko ri arakunrin naa pe, ti wọn si gbọ pe wọn ti gun ni ọbẹ.

Bakan naa ni wọn fikun un pe obinrin to wa ninu ile naa mu ibọn ilewọ lọwọ lai ṣi ilẹkun.

Amọ nigba ti ileeṣẹ ọlọpaa yoo fi de ibe, wọn ba oku ọkunrin ẹni ọdun mọkandinlọgọta ati obinrin ẹni ọ́adọta ọdun ninu ile ibẹ.

Awọn mejeeji ni egbo wa ni ara wọn, ti obinrin naa si ni oju ibọn ni ara rẹ to ṣeeṣe ko yin lu ara rẹ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni iwadii ti bẹrẹ ni pẹrẹwu lori iṣẹlẹ naa.

Amọ wọn ni ohun to sẹeṣe ko waye ni pe obinrin naa gun ọjọgbọn ọkunrin naa pa, ti o si tun pa ara rẹ.

Iṣẹlẹ iku yii ba wa ninu jẹ...

Ileẹkọ fasiti Duquesne Catholic University ṣedaro oṣiṣẹ wọn to papoda ohun.

Ninu atẹjade ti abẹnugan Fasiti wọn, Gabriel Welsch gbe jade ni wọn ti fi ero wọn han.

Ọjọgbọn ni Marinus ni ileẹkọ naa ki o to jade laye, ti wọn si kẹdun pẹlu awọn ọrẹ ati mọlẹbi rẹ.

‘’Ibanujẹ ni eleyii jẹ fun gbogbo ẹni to mọ wọn, adura wa ati ẹbẹ wa pẹlu awọn ọrẹ ati mọlẹbi rẹ.''

Tani Ọjọgbọn Marinus Iwuchukwu?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Marinus Iwuchukwu ni ọjọgbọn onimọ nipa ilana ẹsin ni ileẹkọ Duquesne University, Pittsburgh, Pennsylvania, USA nibi ti o ti n kọ awọn akẹkọọ nipa ijiroro nipa eto isin.

Bakan naa ni wọn tun ma kọ ẹkọ nipa eto ẹsin, ati eto iroyin ati imọ ẹsin.

Ki o to lọ si orilẹede Amerika, fasiti imọ eto ẹkọ ni ipinlẹ Kano ni o ti ṣiṣẹ olukọ fun ọdun mejila.

Ki o to doloogbe ẹkọ imọ ẹsin lagbaye, imọ ominira lati ṣe ẹsin to wu wọn.

Iwe meji lo ti ko, to si tun se agbatẹru fun iwe miran.

Orukọ iwe naa ni : Media Ecology and Religious Pluralism: Engaging Walter Ong and Jacques Dupuis Toward Effective Interreligious Dialogue (2010) ati Muslim-Christian Dialogue for Postcolonial Northern Nigeria: The Challenges of Inclusive Cultural and Religious Pluralism (2013).

O kere tan, o le ni oju iwe ogun ti ọjọgbọn naa ti kọ

Bakan naa lo dari eto ijiroro lori nibi ti wọn ti sọrọ lori ibaṣepọ laarin awọn Kristẹni ati Musulumi ni orilẹede Amerika ati ni Afrika ni ọdun 2010.

Ileeṣẹ ọlọpaa ṣapejuwe awọn mejeeji ti wọn ba oku wọn ninu ile naa gẹgẹ bi ololufẹ, ti wọn si ni iwadii yoo bẹrẹ ni pẹrẹwu lori bi wọn ku.