Ṣíṣe àtìlẹ̀yìn fún olùdíje mìí àti àwọn nkan tí Kwankwaso tún sọ ní Chattam House

Oludije fun ipo aarẹ Naijiria labẹ ẹgbẹ oṣelu NNPP, Rabiu Musa Kwankwaso ti ṣalaye awọn ipinnu rẹ fun orilẹ-ede naa to ba fi wọle sipo aarẹ.
Kwankwaso sọ awọn ọrọ naa lasiko to farahan ni Chattam House nilu London, l’Ọjọru.
O ni ijọba oun yoo gbajumọ eto aabo, ijọba awaarawa, ati igbaye-gbadun araalu.
Sẹnetọ Kwankwaso ni lara erongba oun fun eto aabo, ni lati fi kun iye awọn ọmọ ogun to wa ni Naijiria, titi wọn o fi pọ̀ to lati daabo bo tile-toko ni Naijiria.
“Mo ni imọ pupọ nipa eto aabo -nitori pe mo ti ṣe minisita eto aabo ri, lasiko iṣejọba Aarẹ Oluṣẹgun Obasanjo, ti mo si fun ni awọn imọran to yẹ lati fi opin si iṣoro aabo.”
Lori iroyin to n lọ pe boya yoo jawọ ninu idibo naa lati ṣe atilẹyin fun oludije miran, Rabiu Kwankwaso sọ pe ṣiṣe bẹẹ tumọ si pe oun kii ṣe ọmọ orilẹ-ede Naijiria tootọ.
“Nibi ti nkan de duro bayii, ko si ẹni to fẹ jawọ fun ẹlomii. Gbogbo ipinlẹ ti idibo gomina yoo ti waye ni ẹgbẹ wa ti ni oludije, a si tun ni eeyan 108 to n dije fun ipo sẹnetọ ninu sẹnetọ 109 to wa ni Naijiria.”
O ni jijawọ ninu ere ije fun ipo aarẹ tumọ si pe oun ko nii pa awọn ileri ti oun ṣe fun awọn ọmọ Naijiria mọ́, paapaa ileri ayipada si rere.
Botilẹ jẹ pe ko ni anfaani lati sọ gbogbo nkan to fẹ ẹ ṣe nitori akoko, Kwankwaso sọ pe lẹyin eto aabo, fifi opin si òṣì, atunṣe si eto ilera, adinku si bi nkan ṣe wọn, ati atunto eto ẹkọni ijọba oun yoo gba ju mọ.













