Wo àṣírí bí àwọn 'influencer' ṣe ń gba owó lọ́wọ́ àwọn olóṣèlú láti tako ẹgbẹ́ òṣèlú míì
Ẹka ileeṣẹ iroyin BBC to n ṣe iwadii nipa awọn iroyin ẹlẹjẹ ti tu aṣiri bi awọn alẹnulọrọ lori ayelujara, ti ọpọ mọ si ‘influencers’ ṣe n gba owo gọbọi lọwọ awọn oloṣelu.
Iwadii BBC fi han pe ọpọ awọn alẹnulọrọ naa lo ti gba owo ti iye rẹ to ogun mililọnu naira lati ba orukọ ẹgbẹ kan jẹ.
Pupọ ohun ti awọn awọn eeyan naa maa n ṣe ni ki wọn maa gbe iroyin ẹlẹjẹ lọna ati ṣi ọkan awọn araalu kuro lara ẹgbẹ oṣelu kan lọ si omiran ṣaaju eto idibo.
Lara irufẹ iroyin ẹjẹjẹ ọhun ni bi wọn ṣe sọ pe ọga agba ileeṣẹ Twitter, Elon Must ṣe ailẹyin fun oludije sipo Aarẹ ninu ẹbẹ oṣelu Labour, Peter Obi, ninu fidio kan.
Iwadii wa fi han pe ayederu ni fidio ibi ti Musk ti n ṣatilẹyin fun Obi.
Wayi o, awọn onimọ ti sọ pe irufẹ iwa bẹẹ le ṣakoba fun eto oṣelu ni Naijiria.
Bo tilẹ jẹ pe kii ṣe ẹṣẹ labẹ ofin fun ẹgbẹ oṣelu lati bẹ alẹnulọrọ lawujọ lọwe, ẹṣẹ ni labẹ ofin Naijiria lati maa pin iroyin ẹlẹjẹ lori ayelujara.
Wo fidio oke yii fun ẹkunrẹrẹ.



