Olootu ìjọba UK yóò san owó ìtanràn fún bí ó ṣe kùnà láti lo bẹ́lítì ọkọ̀- Ọlọ́pàá

Aworan

Ileeṣẹ ọlọpaa ti ni Olootu ijọba Rishi Sunak ti ṣe sofin bi o ṣe kuna lati lo bẹliti ninu ọkọ to wa nigba to gbe fọran kan sori ayelujara.

Ọlọpaa Lancanshire ni awọn ti fofin gbe Olootu ijọba, ẹni ọdun mejilelogoji fun iwa naa, ti yoo si san owo itanran.

No 10, ni Sunak ti gba asise rẹ to si ti tọrọ aforijin sugbọn yoo san owo itanran.

Awọn arinrin ajo to ba kuna lati lo bẹliti nigba to wa ni ayika wọn yoo san owo itanran to to ọgọrun un pọun.

Afikun le deba owo naa to to ẹẹdẹgbẹta pọun ti ẹjọ naa ba de ileẹjọ.

Olootu ijọba lo wa ni Lancashire nigba ti wọn ya fọran naa nigba to n rinrin ajo kaakiri ariwa ilẹ London.

Fọran naa ni Olootu agba ṣe lati gbe isẹ ti ijọba ṣe larugẹ lori opo Ayelujara Instagram.

Igba keji ree ti Olootu ijọba yoo maa san owo itanran lati igba to ti de ijọba.

Lọdun to kọja, wọn fi ofin mu oun ati Boris Johnson, Olootu ijọba tẹlẹ ati iyawo rẹ, Carrie lẹyin ti wọn kuna lati tẹle ofin corona nilẹ UK.