A ó fi imú àwọn báǹkì tó ń kó owó naira àtijọ́ sínú ATM wọn dánrin– CBN

New naira notes

Oríṣun àwòrán, @arisetv

Banki apapọ Naijiria ti sọ pe oun yoo fi imu awọn ile ifowopamọ to n ko wo naira atijọ sinu ẹrọ ATM wọn nipinlẹ Ogun danrin.

Ọdun to kọja ni CBN kede owo igba naira, ẹẹdẹgbẹta naira ati ẹgbẹrun kan naira tuntun to si sọ pe ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kini, ọdun 2023 yii ni opin yoo de ba nina owo naira atijọ.

Ni bayii to ku nnkan bii ọsẹ meji ki gbedeke ti CBN fi lede lori owo atijọ naa pe, ọpọ araalu ni ko tii ri owo naa gba.

Ẹwẹ, adari CBN niluu Abeokuta, Lanre Wahab sọ pe awọn yoo fi imu ile ifowopamọ to ba ṣi n ko owo atijọ sninu ẹrọ rẹ danrin.

O ni “Banki apapọ yoo fi iya jẹ ile ifowopamọ to ba ṣi n fun awọn araalu ni owo atijọ ninu ATM wọn.”

Wahab ni CBN yoo bẹrẹ si n yẹ awọn ẹrọ ATM wo lati ri daju pe owo tuntun ti wọn ṣẹṣẹ tẹ lo wa ninu rẹ.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, lati ọjọ kẹtala, oṣu Kini, ọdun 2023 ni CBN ti paṣẹ ki awọn ile ifowopamọ dẹkun ati maa fun araalu ni owo atijọ.

O fikun pe “Eyikeyi ile ifowopamọ ti a ba fiya jẹ lori ọrọ yii, iya naa tọ si irufẹ banki bẹẹ nitori a ti kilọ fun wọn ṣaaju.”

Wahab wa rọ awọn araalu lati maṣe bẹru lati na owo tuntun naa nitori o gba ontẹ ijọba.

Lẹyin naa lo rọ wọn ki wọn tete lọ paarọ owo nairan atijọ si tuntun ko to di ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kini, ọdun 2023 ti wọn yoo fopin si nina rẹ kaakiri Naijiria.