Tí Ọkọ mi kò bá ṣe dáadáa, ẹ lé wa kúrò ní Aso Rock- Iyawo Tinubu

Oríṣun àwòrán, others
Oluremi, iyawo oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oselu APC, Bola Ahmed Tinubu ti rọ awọn ọmọ Naijiria lati kọ yín si ọkọ oun to ba kuna lati ṣe daada tí wọn ba yan gẹgẹ bii aarẹ.
Sẹnẹtọ sọ eleyi nigba to n kopa ninu ìpolongo ibo awọn obinrin fun Tinubu/Shettima niluu Owerri nipinlẹ Imo.
Oluremi ni eto ìdibo lorilẹede Naijiria to n bọ ko gbọdọ dale ọrọ ẹṣin rara sugbọn ipa tí awọn oludije le ko ninu idagbasoke orilẹede Naijiria.
O rọ àwọn ọmọ Naijiria lati fun oludije Musulumi meji laye gẹgẹ bii wọn ṣe fun ẹlẹsin Kristẹni meji laye.
"Ẹ jẹ ka fi ọrọ ẹṣin sì ibi kan, ẹmi gan Kristẹni nimi. Ń jẹ ẹ ti rope ni ìjọ kan Kristẹni meji ko ni jẹ aarẹ.
"A ti dan Musulumi ati Kristẹni papọ, ẹ jẹ ka gbinyanju eleyi naa, lẹyin ọdun mẹrin, tí wọn ko ba ṣe daada, ẹ le wa jade, ẹ kọ yín si wọn."











