Wo àwọn ọkọ̀ bọ̀gìnì tí Laide Bakare, Ibrahim Chatta, Nkechi Blessing àtàwọn míì rà láti mú inú ara wọn dùn

Àwòrán àwọn òṣèré àti ọkọ̀ tí wọ́n rà

Oríṣun àwòrán, Others

Ohun tó kọjú sí èèyàn kan ẹ̀yìn ló kọ sí ẹlòmíràn, bí àwọn ènìyàn kan ṣe ń sọ wí pé ọdún 2022 lágbára tó sì le fún àwọn bẹ́ẹ̀ náà ló jẹ́ ọdún àṣeyọrí fún àwọn mìíràn.

Àmọ́ bí gbogbo rẹ̀ ṣe rí àwọn òsèré kan kọ́lé, àwọn mìíràn ra ilẹ̀ tí àwọn mìíràn sì ra ọkọ̀ bọ̀gìnì.

BBC Yorùbá wá ṣe àkójọ àwọn òṣèré tó ra ọkọ̀ lọ́dún 2022 àti irú ọkọ̀ tí wọ́n rà.

Kolawole Ajeyemi

Lexus GX 460 SUV

Kolawole Ajeyemi àti ọkọ̀ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Instagram

Ọkọ̀ bọ̀gìnì Lexus GX 460 SUV ni Kolawole Ajeyemi fi bẹ̀rẹ̀ ọdún 2022 láti fi ṣàmì ayẹyẹ ogójì ọdún lókè eèpẹ̀.

Nígbà tó ń fi ìròyìn ayọ̀ náà sórí Instagram rẹ̀, Toyin Abraham tó jẹ́ ìyàwó rẹ̀ kí ọkọ̀ rẹ̀ kú oríire lórí àṣeyọrí náà.

Ibrahim Chatta

Chevrolet Camaro RS

Ibrahim Chatta àti ọkọ̀ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Others

Gbajúgbajà òṣèré yìí náà bẹ̀rẹ̀ ọdún 2022 pẹ̀lú bùgá nígbà tó ná ẹ̀gbẹ̀lẹ́gbẹ̀ mílíọ̀nù náírà láti fi ra ọkọ̀ Chevrolet Camaro RS

Nígbà tó ń fi àwòrán ọkọ̀ náà hàn lórí ayélujára Instagram rẹ̀, Chatta ní “gbogbo ọjọ́ ló jẹ́ ẹ̀bùn láti ọdọ̀ Ọlọ́run.” “Mo dúpẹ́ fún Ọlọ́run fún ẹ̀bùn ẹ̀mí.”

Laide Bakare

Lexus RX

Toyota Highlander

Mercedes-Benz GLE-Class

Laide Bakare àti àwọn ọkọ̀ tó rà

Oríṣun àwòrán, Laide Bakare/Instagram

Àrà ọ̀tọ̀ ni Laide Bakare gbé ọ̀rọ̀ tirẹ̀ gbà nígbà tó ra ọkọ̀ bọ̀gìnì méjì pọ̀ lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ tó ṣílé tuntun.

Lexus RX àti Toyota Highlander ni Laide rà papọ̀ ní ọjọ́ kan ṣoṣo nínú oṣù Karùn-ún ọdún.

Nígbà tó tún máa fi di ìparí oṣù Karùn-ún ọ̀hún ló tún ra ọkọ̀ Mercedes-Benz GLE-Class luxury Sports Utility Vehicle (SUV).

Olaiya Igwe

Mercedes GLK SUV

Olaiya Igwe àti ọkọ̀ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Instagram

Àgbà òṣèré Ebun Oloyede tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Olaiya Igwe nínú oṣù Kẹjọ ọdún 2022 rí ẹ̀bùn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, Mercedes-Benz GLK SUV gbà látọwọ́ Musuliu Akinsanya, MC Oluomo.

Níṣe ni Olaiya ń yí nílẹ̀ nígbà tí MC gbé kọ́kọ́rọ́ ọkọ̀ náà fun tó sì fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ awuyewuye lórí ayélujára.

Eniola Badmus

Mercedes-Benz GLE 450 SUV

Ọkọ̀ Eniola Badmus

Oríṣun àwòrán, Instagram

Nígbà tí Eniola Badmus pé ọmọ ọdún márùndínláàdọ́ta nínú oṣù Kẹsàn-án ọdún ló ra ọkọ̀ bọ̀gìnì Mercedes-Benz GLE 450 fún ara rẹ̀.

Eniola Badmus ní òun ni òun máa ma gun ọkọ̀ náà fúnra òun nítorí pé ojú rí tó.

Ó nì kò rọrùn fún òun láti ṣe àmọ́ òun dúpẹ́ pé òun rí nǹkan gbéṣe.

Nkechi Blessing

Range Rover Evoque

Nkechi Blessing ati ọkọ̀ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Instagram

Nkechi Blessing náà ra ọkọ̀ bọ̀gìnì Land Rover Range Rover Evoque tí owó rẹ̀ tó mílíọ̀nù méjìlá náírà.

Nígbà tó ń fi ọkọ̀ náà sórí Instagram rẹ̀, Nkechi Blessing ní òun ta irú ọkọ̀ náà tí òun ní tẹ́lẹ̀ lọ́dún 2021 láti fi parí ilé rẹ̀ tó kọ́.

Shan George

Mercedes-Benz GLK 350 SUV

Shan George ati ọkọ̀ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Instagram

Nínú oṣù Kejìlá tó ṣẹ̀ṣẹ̀ parí yìí ni gbajúgbajà òṣèré Shan George náà di ọ̀kan lára àwọn òṣèré tó ń lo mẹ̀sí ọlọ́yẹ́.

Shan George ní àwọn ọmọ òun ra ọkọ̀ Mercedes-Benz GLK 350 SUV fún òun gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn ọdún kérésìmesì.

Mercy Chinwo

Toyota Land Cruiser

Mercy Chinwo àti ọkọ̀ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Instagram

Nínú oṣù Kẹsàn-án ọdún 2022 ni gbaajúgbajà olórin ẹ̀mí Mercy Chinwo gba ẹ̀bùn ọkọ̀ bọ̀gìnì Toyota Land Cruiser lọ́wọ́ ọkọ rẹ̀ fún ayẹyẹ ọjọ́ ìbí tọ ṣe.

Nígbà tó fi àwòrán ọkọ̀ náà sórí Instagram rẹ̀, Chinwo ní kí àwọn ènìyàn bá òun dúpẹ́ lọ́wọ́ ọkọ òun fún ẹ̀bùn náà.

Ó ní ẹ̀bùn tó dùn mọ́ òun nínú jùlọ ni òun rígbà náà.

Wizkid

Ọkọ̀ Wizkid

Oríṣun àwòrán, Instagram

Ninu oṣù Kẹsàn-án ọ̀hún bákan náà ni Gbajúgbajà olórin tàkasúfèé, Ayodeji Ibrahim Balogun tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Wizkid ná owó tó bílíọ̀nù kan náírà lórí ọkọ̀ bọ̀gìnì méje.

Rolls-Royce Cullinan, Lamborghini Aventador àti Mercedes-Maybach Van ló fi owó náà rà.

Timaya

Ferrari 458

Ọkọ̀ Timaya

Oríṣun àwòrán, Instagram

Nínú oṣù kẹfà ọdún 2022 ni gbajúgbajà olórin tàkasúfèé, Inetimi Alfred Odon tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Timaya ra ọkọ̀ tuntun, ìyẹn Ferrari 458.

Timaya fi àwòrán ọkọ̀ náà sórí Instagram rẹ̀ pé òun fi ọ̀rẹ́bìnrin òun kalẹ̀ tí òun sì mú ọmọ tuntun.