Ìjọba South Africa já iná mọ̀nàmọ́ná ‘embassy’ Naijiria lẹ́yìn to jẹ gbèsè $23,000 owó iná

South Africa restores electricity to Nigeria consulate

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Wọn ti da ina mọnamọna pada si ọofisi ijọba Naijiria to wa niluu Johannesburg, ni South Africa bayii lẹyin ti wọn kọkọ ja ina ọhun.

Eredi ti wọn ṣe ja ina naa ko ṣeyin gbesẹ ẹgbẹrun lọna irinwo rand, $23,000 owo ilẹ naa ti ọọfisi ijọba Naijiria jẹ.

Ṣaaju ni awọn oṣiṣẹ ọọfisi ijọba Naijiria naa ti kọkọ kọ jalẹ lati jẹ ki awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ mọnamọna wọ ọgba wọn.

Lẹyin eyi ni ileesẹ mọnamọna naa lọ ja ina ọuhn lati ori ẹrọ kọmputa ileeṣẹ wọn.

Lẹnu lọlọ yii ni ileeṣẹ mọnamọna ni South Africa bẹrẹ si n ja ina awọn ileeṣẹ to kọ lati san owo ina ti wọn lo.

Iroyin ni apapọ iye gbese ti awọn eeyan jẹ ileeṣẹ naa ko din ni òjìlénígba dín mẹ́jọ dọla, ($232m).

Amọ ṣa, lẹyin ti wọn ja ina ọọfisi ijọba Naijiria tan, a gbọ pe aṣoju ijọba Naijiria si orilẹ-ede naa lọ san ẹgbẹrun meje dọla lara owo ina ti wọn jẹ.

Lẹyin naa lo tun ṣeleri pe ijọba Naijiria yoo san owo to ku titi ipari oṣu yii.

Eredi ree ti wọn fi da ina ọhun pada lọjọ kan naa.

Ọpọ awọn ọmọ Naijiri lo ti bẹrẹ si n bu ẹnu atẹ lu ijọba fun iṣẹlẹ ọhun bayii.

Lawa awọn ohun ti wọn n sọ ni pe itiju nla ni ọrọ naa jẹ pe ọọfisi ijọba Naijiria n jẹ gbese owo ina loke okun.