APC Osun kéde aàwẹ̀ àti àdúrà ọjọ́ méje kí 'tribunal' lè gbé ipò gómínà padà fún Oyetola

Oyetola, Adeleke

Oríṣun àwòrán, @Naija_PR

Ẹgbẹ oṣelu APC ipinlẹ Osun ti ke si awọn ọmọ ẹgbẹ naa kaakiri ipinlẹ ọhun lati bẹrẹ awẹ ati adura ọlọjọ meje lati wa oju rere Ọlọrun ninu idajọ ile ẹjọ to n gbọ ẹjọ idibo gomina ipinlẹ naa.

Oni, ọjọ Ẹti, ogunjọ, oṣu Kini, ọdun 2023 lo yẹ ki awẹ ati adura naa bẹrẹ.

Ile ẹjọ naa ti gbọ ẹjọ ti gomina ana, Gboyega Oyetola pe tako Ademola Adeleke, ninu eyii ti Oyetola ti n bere pe ko kede oun gẹgẹ bii ojulowo ẹni bori idibo ọhun, ki oun le pada sipo gomina.

Ọjọ kẹrindilogun, oṣu Keje, ọdun 2022 ni idibo gomina ọhun waye.

Wayi o, ile ẹjọ ti gbọ atotonu awọn agbẹjọro Oyetola ati Adeleke tan, o si ti n mura lati dajọ ni ipari oṣu Kini ọdun yii.

Ko si ohun ti Ọlọrun ko le ṣe – APC

Ninu atẹjade kan ti alaga fidihẹ ẹgbẹ oṣelu APC ipinlẹ Osun, Tajudeen Lawal fi lede, o ni ṣe pataki fun awọn ọmọ ẹgbẹ naa lati gbadura ati awẹ ki wọn le ri oju rere ninu idajọ ile ẹjọ ọhun.

Ninu atẹjade naa ni Lawal ti sọ pe ko si ohun to le koko ti agbara adura ko le yanju.

Atẹjade ọhun ni “Alaga ẹgbẹ wa ni oun gbagbọ pe ko si ohun to le ju agbara adura lọ.”

“O parọwa si awọn ọmọ ẹgbẹ APC lati maṣe fi ọwọ yẹpẹrẹ mu adura naa.”

“O fi kun pe oun ni igbagbọ ninu Ọlọrun pe Ọlọrun ti oun n sin ko ni ja oun kulẹ lailai.”

Lawal ninu atẹjade naa tun rọ awọn ọmọ ẹgbẹ APC lati ṣisẹ takuntakun fun aṣeyọri ẹgbẹ ọhun ninu eto idibo Aarẹ to n bọ kankan.

Lẹyin naa lo tọka si ọrọ inu Bibeli ni iwe Efesu 6:12 to sọ pe “Nítorí pé kì í ṣe ẹ̀jẹ̀ àti ẹran-ara ní àwa ń bá jìjàkadì, ṣùgbọ́n àwọn ìjòyè, àwọn ọlọ́lá, àwọn aláṣẹ ìbí òkùnkùn ayé yìí, àti àwọn ẹ̀mí búburú ní ojú ọ̀run.”