Àjọ NDLEA ṣàwárí egbògi olóró Tramadol, Opioid tó tó N5b ni Eko

Oríṣun àwòrán, others
lIleeṣẹ to gbogun ti egbogi oloro lorilẹede Naijiria NDLEA tí kede pe awọn ti ṣawari egbogi oloro Tramadol ati ọpọlọpọ Opioid toto bilọnu maraun un naira ni ile gbe kan ń ipinlẹ Eko.
Bakan naa ni ajọ ọhun tun kede ọwọ tẹ meji lara awọn afurasi ọdaran ti wọn hu iwa ọdaran naa eyi to lodi sì ofin orilẹede Naijiria.
Agbẹnusọ ajọ naa, Femi Babafemi, ninu atẹjade to fi lede niluu Abuja ni awọn ṣawari awọn egbogi oloro naa ni agbegbe Amuwo Odofin nipinlẹ Eko.
Babafemi ni ẹni to ni ile naa, Aloysius Okeke wa lara awọn ti ọwọ tẹ.
O ni gbogbo egbogi oloro Tramadol tí awọn ṣawari ninu ile naa to milọnu mẹta ati abọ pẹlu ọpọlọpọ egbogi oloro Codeine.
"Kete ti a mu afurasi kan Olanrewaju Lawal Wahab, ẹni to pin awọn egbogi oloro naa lọjọ naa.
" A gba ọkọ ayọkẹlẹ to fi n pin egbogi oloro ọhun kiri pẹlu igo Codeine tótó ẹgbẹrun mẹrinla.
"402,500 tabilẹti tramadol 250mg; 50,000 tabilẹti tramadol 225mg ati 210,000 kapsul pregabalin 300mg,”
Babafemi ni Ọga agba fun ajọ ọhun, Brig Gen Buba Marwa ti kan sara awọn ọmọ ajọ naa nipinlẹ Eko fun isẹ takuntakun tí wọn ṣe lati ṣawari awọn afurasi ọdaran naa.
Marwa wa rọ awọn ọmọ ogun lati dẹkun ṣíṣe isẹ fifọ ilu mọ eyi ti wọn gunle.















