Àwọn iléẹjọ́ Sharia rí ẹ̀wọ̀n he lórí ẹ̀sùn pé wọ́n gba rìbá N500m

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ileẹjọ magisreti nipinlẹ Kano ti paṣẹ pe ki awọn adajọ ni ilẹẹjọ Sharia lọ fi ẹwọn jura lori ẹsun pe wọn ji owo to to ẹẹdẹgbẹta miliọnu naira, N500 million.

Adajọ ileẹjọ ọhun lo sọ bẹẹ lasiko to n da ẹjọ lori ẹsun ti wọn fi kan wọn oṣiṣẹ ileẹjọ Kano State Sharia Court Division pe wọn lu owo awọn alaini ni ponpo.

Ẹsun ti wọn fi kan awọn mẹrinla ti ọrọ kan ni ole jija, piparọ, yiyi iwe ati iwa ọdaran.

Ẹsun ti wọn fi kan wọn...

Adajọ Mustapha Sa’ad Datti lasiko to n ka idajọ rẹ ni ẹṣun wọn tako iwe ofin iwa ọdaran ti section 97, 79, 315 ati 289.

Adajọ ni awọn adajọ ileẹjọ Sharia naa ati awọn oṣiṣẹ yi iwe lati ji owo to wa ni ikawọ wọn.

‘’Ọdun 2021 ni wọn kọkọ mu ẹjọ wa pe Bashir Ali Kurawa, Saadatu Umar, Tijjani Abdullahi, Maryam Jibrin Garba, Shamsu Sani ati Hussaina Iman to jẹ Cashier sise papọ lati fi ẹtọ awọn eniyan dun wọn.’’

‘’ohun ti wọn ṣe ni pe wọn lo ipo wọn lati de adakọ iwe aṣẹ ileẹjọ Sharia to n gbọ ẹjọ kotẹmilọrun, ti wọn si ṣe ayederu ontẹ awọn meji to ni aṣẹ si apo iṣuna ileẹjọ naa, ti wọn si pin owo naa fun ara wọn.’’

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Owo naa ni wọn ni o yẹ ko jẹ fun awọn ọmọ alaini baba, ti iye owo naa jẹ ẹẹdẹgbẹta miliọnu naira.

Bakan naa ni wọn tun fi ẹsun kan wọn pe, laarin ọdun 2018 si 2021, won tun ṣe iwa ti ko tọ.

Wọn ni pe awọn oṣiṣẹ yi: Sani Ali Muhammad, Sani Buba Aliyu, Bashir Baffa, Garzali Wada, Hadi Tijjani Mu’azu, Alkasim Abdullahi, Yusuf Abdullahi.

Ati Mustapha Bala Ibrahim, Jafar Ahmad, Adamu Balarabe, Aminu Abdulkadir, Abdullahi Suleiman Zango, Garba Yusuf, Bashir Ali Kurawa ati Hussaina Imam tun pawọpọ ji owo.

Owo awọn ayederu oṣiṣẹ ti wọn ni wọn n ṣiṣẹ nibẹ ti wọn si ti ku (ghost workers) ni wọn tun ji gbe

Adajọ sun igbejọ di Osu keji, ọdun 2023

Lasiko igbẹjọ wọn ni marundinlogun ninu wọn sọ pe awọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Lẹyin naa ni agbẹjọro wọn wa beere fun ileẹjọ lati gba beeli wọn.

Adajọ Mustapha Datti ti wa fun igbẹjọ siwaju di Ọjọ Kini, Oṣu Keji, ọdun 2023.