Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá pín ₦13b fún mọ̀lẹ́bí àwọn ọlọ́pàá tó kú sẹ́nu iṣẹ́

Oríṣun àwòrán, Nigerian police force/Facebook
Ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, Usman Baba, ti pin owo ti iye rẹ le ni biliọnu mẹtala naira fun awọn mọlẹbi awọn ọlọpaa to padanu ẹmi wọn lẹnu iṣẹ.
Usman Baba lakoko to n pin iwe sọwe-dowo naa ni olu ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe owo naa wa fun awọn oṣiṣẹ to le ni ẹgbẹrun mẹfa ti wọn ti jade laye laarin ọdun 2012 si ọdun 2020.
O ni lati igba ti oun ti di Ọga agba ọlọpaa lọdun 2021 ni wọn ti pe akiyesi oun si ajẹẹlẹ to yẹ fun awọn ọlọpaa to padanu ẹmi wọn lẹnu iṣẹ ati awọn to fara ṣeṣe.
Usman ni kiakia ni oun fi to aarẹ Muhammadu Buhari leti, ti o si paṣẹ ki wọn san awọn ẹtọ to ṣe pataki fun awọn ọlọpa to ti padanu ẹmi wọn lẹnu ise.

Oríṣun àwòrán, Nigeria police Force/Facebook
Ti ẹ ko ba gbagbe, itọju awọn oṣiṣẹ ọlọpaa wa lara awọn ibeere awọn ọdọ Naijiria lakoko iwọde #EndSARS ninu oṣu Kẹwaa, ọdun 2020.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Nigba ti o n sọrọ, Ọga agba ọlọpa tun ni igbayegbadun awọn ọlọpaa ṣe koko.
Bakan naa lo tun ba awọn idile awọn oṣiṣẹ to padanu emi won kẹdun, o si rọ wọn lati lo owo ti wọn gba daadaa.












