"Ẹ tú ìgbeyàwó wa ká torí ọkọ mi pè mí ní ẹrú"

Arabinrin kan ti o n wa ikọsilẹ laarin oun ati ọkọ rẹ Sadinatu Adamu, ti sọ fun ile-ẹjọ agbegbe Upper Mararaba, ni ipinlẹ Nasarawa pe ọkọ oun, Yakubu Abdulmajid pe oun ni ẹru.
Sadinatu, ninu iwe ẹsun to fi kan ọkọ rẹ ni Yakubu ko ṣe deede, bẹẹ si ni o maa n na oun, ti oun ko si ni ayọ ati alafia ninu ibagbepọ awọn.
Sadiatu ni Oṣu Kẹrin ọdun 2017 ni oun fẹ Yakubi gẹgẹbi ofin Islam ati asa ti Ankpa ni Kogi ati pe ọmọ meji lo wa laarin awọn mejeeji.
Sadiatu ni “Ọkọ mi maa n lu mi, ti o ṣi tun naa n fi mi ṣe ẹlẹya, mo bẹru pe ni ọjọ kan yoo pa mi.
O ni bẹliti ati igi ni Yakubu fi n maa n lu oun ni gbogbo igba.
Sadiatu ni “Mo sọ fun awọn ìdile ọkọ mi, ṣugbọ́n wọn ko le yi ọkan rẹ pada ti o si halẹ lati pa mi,”
Olupẹjọ naa bẹ ile-ẹjọ lati tu igbeyawo wọn ka, ko si paṣẹ fun Yakubu lati gba oun laaye lati ko awọn nkan to ku ninu ile rẹ.
Yakubu ẹni to wa ni ile ejọ naa ko tako ẹsun ti wọn fi kan.
Adajọ, Mohammed Jibril wa sun igbẹjọ siwaju.














