Ẹ̀yin ọmọ Naijiria, ẹ máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun – Aarẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, Others
Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti kesi awọn ọmọ Naijiria lati dupẹ lọwọ Edua fun ọrẹ to n ṣe fun orilẹede ọhun.
Aarẹ Buhari ni awọn iṣẹ akanṣe ‘’infrastructure’’ ti ohun waye lorilẹede Naijiria kọja afẹnusọ, to si n wuni lori.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ fun aarẹ Buhari, Femi Adesina fi lede ni awọn ọmọ Naijiria gbọdọ mọ ore nipa awọn iṣe akanṣe ti ijọba n kọ fun wọn.
Lasiko ti aarẹ Buhari n ṣi awọn iṣẹ akanṣe ni ilu Kano ni aaṛẹ ti sọ ọrọ yii.
‘’Idi niyii to yẹ ki awọn ọmọ Naijiria maa dupẹ...’’
Buhari ni ti a ba wo awọn ohun ti orilẹede naa n la kọja, to fi mọ orilẹede miran, o yẹ ki wọn dupẹ lọwọ Ọlọrun.
‘’O ṣeni ni aanu pe awọn ọmọ Naijiria ko mọ riri orilẹede ti wọn wa, orilẹede yii ni ohun meremere’’
''O di igba ti ẹ ba lọ si orilẹede miran ki eto mọ ohun pe o yẹ ki ẹ dupẹ lọwọ Edua to da yin si orilẹede Naijiria.''

Oríṣun àwòrán, Others
Buhari tun sọ pe:
‘’Bi mo ṣe n fo lori ofurufu ti mo ri awọn ile nla nla, awoṣifila loju popo, mo mọ pe o yẹ ka dupẹ lọwọ Ọlọrun.’’
Bakan naa ni aarẹ parọwa si awọn agbalagba lati kesi awọn ọdọ ki wọn gba eto ẹkọ laaye, ki wọn lọ si ileẹkọ nitori imọ erọ ti mu ohun gbogbo rọrun fun awọn eniyan.
Aarẹ Buhari tun ki gomina ipinlẹ Kano, Abdullahi Umar Ganduje ku oriire fun awọn iṣe akanṣe to n lọ lọwọ ni ilu ọhun.












