Ohun tí òníbàárà wa fẹ́ sọ ni "Popsy" kìí ṣe "Pussy" - Ọmọ ilé ẹ̀kọ́ Poly Nekede rí àgbẹjọ́rò

Ọmọ ile ẹkọ Poly Nekede

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Yoruba bọ wọn ni ko ni buru titi ko ma ku ẹnikan mọ ni. Ọmọ ile ẹkọ gbogboniṣe Nekede to wa ni ipinlẹ Owerri ti ri ẹlẹyinju aanu agbẹjọro ti yoo gbeja rẹ lori akoba to ṣe si ara rẹlori fidio Tiktok eyi to ti wọ ọ de iwaju aọn alaṣẹ ile iwe rẹ.

Agbẹjọro naa ti kọ iwe ẹjọ si awọn alaṣẹ ile iwe rẹ to si ni onibaara ile iṣẹ awọn ko mọọmọ fẹ tabuku ba orukọ ati iyi ile iwe naa.

Gẹgẹ bo ṣe wa ninu ọrọ ti wọn kọ ranṣẹ:

“Awa ni agbẹjọro Okereafor Ogechi Sharon. A gbọ pe yoo foju han niwaju igbimọ alaṣẹ afiyayajẹni ti ile iwe yin a si fẹ lo anfani yii lati fi igboya wa han ninu pe igbimọ naa yoo ṣe iṣẹ wọn ni ibamu pẹlu ofin igbọniye ati idajọ ododo lai ko eeyan laya jẹ.”

Ṣaaju ni fidio kan ti kọkọ gba igboro kan ninu eyi ti arabinrin Sharon ti sọ ọrọ ti ọpọ awọn eeyan to woo tumọ rẹ si pe o ni ọpẹlọpẹ Ọlọrun ati nnkan ọmọbinrin oun ni oun fi kẹkọ pari ni ile ẹkọ oun.

Wọn kọ siwaju ninu iwe wọn pe awọn ti ba onibara awọn ni ọrọ pọ ti ẹri to wa niwaju awọn si fihan pe arabinrin naa ko ni erongba kankan lati ba orukọ tabi iyi ile iwe naa jẹ.

“Gẹgẹ bi ọrọ rẹ, ohun to wa ninu fidio to gba ori ayelujara kan jẹ aṣilo ahọn nitori bi inu rẹ ṣe dun ladunju pe o kawe ja. Ọrọ to fẹ sọ gangan ni pe “...Ọlọrun ati Pupsy” iyẹn Baba gẹgẹ bi ọkan imoore si Ọlọrun Ọba ati Baba rẹ.

O fihan pe ko ni ero kankan lati lo ọrọ alufansa ninu fidio ọhun fi ba ti ile iwe jẹ, nitori ko darukọ olukọ kankan tabi orukọ ileewe ninu fidio naa.”

Ẹwẹ, lẹta naa sọ pe awọn agbẹjọro awọn ti wa nikalẹ ni ile ẹkọ naa lati bojuwo bi ifarahan onibara wọn ṣe n lọ niwaju igbimọ lati ma kẹẹfin idẹrubani tabi ifiyajẹni kankan.

Agbẹjọro to n lewaju gbigbeja arabinrin Sharon ni orukọ rẹ n jẹ Ikechukwu Nwaopara to jẹ oṣiṣẹ ile ẹjọ giga julọ ni Naijiria.

‘Ọpẹ́lọpẹ̀ “Ojú ara” mi àti Ọlọ́run ni mo fi “graduate’ - Ọmọ ile ẹ̀kọ́ kéde lórí ‘Tiktok’, ó wọ gàù!

Nikede Polytechnic Owerri

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ile ẹkọ gbogboniṣe Nekede ni ipinlẹ Owerri ni awọn ti n tọpinpin ẹni pato ti ọkan lara awọn ọmọ ile ẹkọ kan jẹ to bọ si oju opo Twitter lati sọ pe iranlọwọ Ọlọrun ati nnkan ọmọbinrin oun lo jẹ ki oun kẹkọ oun ja.

Ninu fidio kan to gba oju opo ayelujara Tiktok pẹlu @sharon_moni ni arabinrin naa ti n fi inu didun sọrọ idagbere si Nekede lẹyin to pari akanṣe iwe kikọ rẹ fun kilasi aṣekagba Higher National Diploma (HND).

Ẹwẹ, ninu atẹjade ti ọkan lara awọn alakoso ile ẹkọ giga naa fọwọ si, Arabinrin E.C Anuna sọ pe awọn ko tẹwọ gba iwa ti ọmọ ile ẹkọ naa hu rara.

“Eyi ni lati fi to gbogbo eniyan leti pe awọn alaṣẹ ile ẹkọ gbogboniṣe Nekede ti bẹrẹ iwadii kikun nipa ọmọ ile ẹkọ to n sọrọ odi fi buga lori ayelujara Tiktok lori bo ṣe kẹkọọ gboye nipa iranlọwọ Ọlọrun ati ọpẹlọpẹ nnkan ọmọbinrin rẹ.

O tilẹ jẹ ọrọ odi ko si ba iṣedaadaa mu pe ọmọ ile ẹkọ n fi orukọ Ọlọrun ọba ta ayo to si n yii mọ iwa aburu tirẹ,” atẹjade naa ṣalaye.

Ile ẹkọ Poly naa ni iṣedeede ile ẹkọ awọn tayọ gidi gan ni ti wọn si fi kun un pe ati awọn oṣiṣẹ to fi mọ awọn ọmọ ile ẹ̀kọ́ lo mọ àtúbọ̀tán iru iwa àṣemáṣe bayii.

Wọn ní ìwà ti arábìnrin náà hu ko fọ ire nipa ile ẹ̀kọ́ wọn.

"Oludari ilé ẹ̀kọ́ náà to jẹ Alufa ni ifarajin si gbingbin ẹ̀kọ́ iwa ọmọlúwàbí sinu awọn ọmọ ile ẹ̀kọ́ nipasẹ awọn àkànṣe eto apero, ìsìn àdúrà, ilaniloye ati ìpolongo". Atẹjade naa sọ bẹẹ.

Ọmọ ile ẹ̀kọ́ náà ti tuba?

Arabinrin ti ọrọ kan ti sọ̀rọ̀ nínú iforowanilenuwo kan lórí Rédíò Darling FM pé ohun tí òun sọ nínú fídíò to gbòde kan gan ni "Ọlọ́run ati 'popsy'" to si wa jọ pe nnkan míì ni oun sọ.

O ni látìgbà tí òun ti wọ ile ẹ̀kọ́ gíga, ọ̀rẹ́kùnrin kan ṣoṣo ni oun ni bẹẹ si ni oun ko tilẹ̀ mọ awọn olùkọ́ òun.

"Mo tọrọ aforijin ẹyin ọmọ Naijiria, awọn eeyan ṣi mi gbọ́ ni ".

"Fi idi gba maaki - Ṣe ofin fàyè gba a?

Iwa ki eeyan kan máa fi ibalopọ gba maaki lọwọ olùkọ́ jẹ irufin ńlá gbáà láwọn ile ẹ̀kọ́ gíga Naijiria bẹẹ si ni olùkọ́ tí àwọn aláṣẹ ba gba mu yoo padanu isẹ rẹ.

Kii ṣe igba àkọ́kọ́ niyi ti awọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ giga maa n fi ilọkulọ ibalopọ lọ awọn ọmọ ile ẹ̀kọ́ ki wọn le jẹ ki wọn ní maaki láti yege nínú ẹ̀kọ́ tí wọn ba n kọ wọn.