Àwọn agbébọn ṣíná ìbọn bolẹ̀ níbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí, èèyan mẹ́jọ jáde láyé

South Africa birthday party shooting

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Eeyan mẹjọ ti ku nigba ti awọn mẹrin mii farapa yanayana lẹyin ti ọkunrin meji kan ṣina ibọn bolẹ niluu Gqeberty, lagbegbe Eastern Cape, ni South Africa.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ṣe ni awọn ọkunrin meji naa dede dana ibọn ya awọn eeyan kan to pejọ ti wọn n ṣe faaji nibi ayẹyẹ ọjọ ibi kan.

Titi di akoko ti a n ko iroyin yii jọ, ọwọ ko tii tẹ awọn agbebọn naa, amọ wọn ti n wa wọn.

Bo tilẹ jẹ pe wọn ko tii kede orukọ awọn to ba ikọlu ọhun lọ, ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe ẹni to ni ile ti ikọlu naa ti waye wa lara wọn.

Kọmiṣọna ọlọpaa agbegbe Eastern Cape, Nomthetheleli Lillian Mene sọ fun awọn akọroyin pe “ọdaran ni awọn to ṣekupa awọn eeyan naa, a ko si ni sinmi titi ti ọwọ yoo fi tẹ wọn.”

Minisita fun ọrọ awọn ọlọpaa, Bheki Cele ti ṣabẹwo sibi ti iṣẹlẹ ọhun ti waye, o si ti rọ awọn araalu ki wọn lọ ni suuru bayii ti iwadii ti bẹrẹ.

O ni “a mọ pe inu n bi gbogbo eeyan, o si wu wa ki a gbe igbesẹ ni kiakia amọ a nilo akoko diẹ lati ṣe iwadii lẹkunrẹrẹ.

Orilẹ-ede South Africa jẹ ọkan lara awọn orilẹ-ede ti wọn ti n dede ṣina ibọn fun awọn araalu julọ lagbaye.

Lọdun to kọja, wọn ṣina ibọn fun awọn eeyan kan nile ọti nibi ti ẹmi ogun eeyan ti sọnu.

Wọn ṣi n ṣewadii iṣẹlẹ naa titi di akoko yii.