Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n sọ fún mi pé mi ò lè làlùyọ nídìí iṣẹ́ tíátà - Lateef Adedimeji

Lateef Adedimeji

Oríṣun àwòrán, Lateef Adedimeji/Instagram

Yorùbá bọ̀ wọ́n ní ojú ẹni ma là á rí tó.

Tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn gbájúmọ́ ènìyàn bá tẹnu bọ nǹkan tí wọ́n là kọjá kí wọ́n tó di ẹni ayé ń fẹ́, ilẹ̀ a kún.

Báyìí ni ọ̀rọ̀ rí nígbà tí gbajúgbajà òṣèré tíátà, Lateef Adedimeji ṣàlàyé ohun tí ojú rẹ̀ ní nídìí iṣẹ́ tíátà tó yàn láàyò kó tó di ẹni tí ayé ń fẹ́.

Lateef tó kọ ọ̀rọ̀ nípa bó ṣe bẹ̀rẹ̀ eré tíátà ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ kó tó di ìlú mọ̀ọ́kà ní ohun tí ojú ohun rí kò kéré rárá.

Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni wọ́n ti sọ fún òun pé iṣẹ́ tíátà kìí ṣe ọ̀nà òun kí òun lọ wá nǹkan mìíràn ṣe nítorí òun kò lè ní àṣeyọrí nídìí iṣẹ́ náà.

Lateef tó kọ àwọn ọ̀rọ̀ náà bó ṣe ń kí ara rẹ̀ kú ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ní òun fẹ́ fi ìtàn òun ṣe ìwúrí fún àwọn olólùfẹ́ òun ni pé kí wọ́n má kò àárẹ̀ ọkàn nídìí iṣẹ́ tàbí òwò tí wọ́n bá yàn láàyò.

Láti kékeré ni mo ti máa ń pa àwọn ènìyàn lẹ́rìn-ín

Ó ṣàlàyé pé láti ìgbà tí òun ti wà ní kékeré ni òun ti máa ń pa àwọn ènìyàn lẹ́rìn-ín tí òun kàn sì máa ń ṣe tòun láì mọ̀ wí pé ó máa di nǹkan ńlá báyìí fún òun.

Lateef ní ìṣe òun yìí ni àjọ elẹ́yinjú àánú kan fi mú òun nígbà tóun wà ní ilé ẹ̀kọ́ girama láti kọ́ òun nípa orin, ijó àti eré tíátà.

Ó ní inú òun dùn wí pé òun kò kó àárẹ̀ ọkàn pẹ̀lú gbogbo nǹkan tí òun dojú kọ nígbà tí òun wà ní ilé ẹ̀kọ́ gíga títí tí òun fi parí.

Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mi ò ní lówó ọkọ̀ láti lọ sí oko eré

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Gbajúmọ̀ òṣèré náà tún ṣe ìrántí ìgbà tí òun kò ní ní owó ọkọ̀ láti lọ sí oko eré tó jẹ́ wí pé òun máa rìn lọ síbẹ̀ láì ní gba kọ́bọ̀ gẹ́gẹ́ bí owó iṣẹ́.

Bákan náà ló ní yàtọ̀ sí owó, ọ̀pọ̀ ìgbà ni òun máa yá aṣọ wọ̀ láti lọ kópa nínú eré.

"Mo rántí ìgbà tí wọn kò gbàmí sí iṣẹ́, tí wọ́n búmi pé iṣẹ́ tíátà kìí ṣe ọ̀nà mi, pé mi ò le làlùyọ nídìí rẹ̀."

"Mo rántí ìgbà tí mo fẹ́ pinnu láti fi iṣẹ́ tíátà sílẹ̀, tí mo sunkún lọ́pọ̀ ìgbà pé ikú yá ju ẹ̀sín lọ."

"Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ si ni gba ẹgbẹ̀rún kan náírà sí ẹgbẹ̀rún márùn-ún náírà, ìdùnnú àti ayọ̀ ni mo fi máa ń gba owó náà nígbà náà lọ́hùn-ún."

Ó ní òun dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ìrìnàjò òun láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ fún àánú àti ìbùkún rẹ̀ tí òun rí gbà lónìí.

Lateef Adedimeji ní kò sí ohun tí ènìyàn lè máa dojú kọ lónìí, tí ènìyàn kò bá ti kó àárẹ̀ ọkàn ọ̀nà yóò padà là fún onítọ̀hún.