Àwọn èèyàn ń fi ẹsẹ̀ rin fún ọjọ́ mẹ́sàn án nítorí àti rí Pope Francis ní South Sudan

Awọn ero to n rin lọ si Juba lati pade Poopu Francis

Ọpọ eeyan lo ti n ya bo ilu Juba tii ṣe olu ilu orilẹede South Sudan lati lee lọ ki olori ijọ Aguda lagbaye, Poopu Francis lasiko to ba gunlẹ sibẹ lọjọ Ẹti.

Poopu Francis yoo rinrinajo lati orilẹede Democratic Republic of Congo pẹlu iṣẹ alaafia si orilẹede naa nibi ti wahala ati hilahilo ti n gbalẹ sọ.

BBC ṣe alabapade awọn ọmọ ijọ Katoliiki kan ti wọn ti n fi ẹsẹ rin fun ọjọ mẹsan an lati Rumbek to wa ni iwọ maili aadọwa (190miles) lẹkun iwọ oorun ariwa ilu Juba.

"Ohun gbogbo ti Poopu ba gbadura le lori ni yoo wa si imuṣẹ"

“Bi ẹmi naa ba wa ninu rẹ, ko lee rẹ ọ. Awa wa lati gba ibukun lati ẹnu Poopu. O si da mi loju pe pẹlu ibukun rẹ, nnkan yoo yipada fun orilẹede yii,” ni ọrọ ti arabinrin kan sọ fun BBC.

Wahala ogun abẹle ati dukuu ọdun gbọgbọrọ lagbo oṣelu ti fẹ fa orilẹede South Sudan ya lati igba to ti gba ominira lọdun 2011.

Aworan Poopu Francis ati aarẹ South Sudan lori patako ipolongo kan

Ọpọ lo n wo ijọ Kristi gẹgẹ bi orisun ireti. Ibẹ si ni ọpọ fara pamọ si nigba ti ogun bẹ silẹ.

Ọpọ eeyan lorilẹede naa lo si ni igbagbọ pe irinajo Poopu ijọ Katoliiki si orilẹede naa yoo mu ayipada ba orilẹede wọn.

“Wolii ni, ohun gbogbo to ba si gba ni adura ni ọjọ diẹ to ba fi wa lori ilẹ wa yoo wa si imuṣẹ. Nnkan yoo yipada. Iṣọkan yoo de ba awọn eeyan ilẹ yii.”

Igbagbọ ọpọ awọn ọmọ South Sudan ni pe abẹwo Poopu yoo dẹkun ogun ati ọtẹ nibẹ

Awọn ero to n rin lọ si Juba

Lọdun 2019, Poopu fi ẹnu ko ẹsẹ awọn meji to n lewaju igun oṣelu to n fija pẹẹta lorilẹede naa, iyẹn aarẹ Salva Kiir ati igbakeji rẹ Riek Machar nigba ti wọn pade ni ilu Vatican.

Igbesẹ naa ya ọpọ lẹnu nigba naa bi o tilẹ jẹ wi pe ko tan wahala aarin wọn.

Ọjọ mẹta ni ireti wa pe olori ijọ Aguda lagbaye, Poopu Francis yoo lo lorilẹede South Sudan, yoo si ṣe iṣẹ isin nibẹ lọjọ Aiku.

Oun atawọn adari ijọ kristiẹni meji miran ni yoo wa lorilẹede South Sudan – lati ijọ Anglican ati ijọ Presbyterian.