Ẹ kàn fún mi ní ọjọ́ méje láti yanjú ọ̀wọ́ngógó Naira yìí - Buhari sí gbogbo ọmọ Nàìjíríà

Aarẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, Presidency

Ààrẹ orílẹ̀èdè Naijiria, Muhammadu Buhari ti ni ki awọn ọmọ Naijiria fun oun ni ọjọ meje lati fi yanju gbogbo wahala ti ọ̀wọ́ngogo owo naira tuntun da silẹ lẹ́nu ọjọ díẹ̀ ti owo naa yọjú síta.

Eyi jẹ jade nibi ipade to ṣe pẹlu ẹgbẹ́ awọn gomina APC nile Ààrẹ latari ati wa ọna àbáyọ si bi owo yii ṣe n ha ti ko de ọwọ awọn ọmọ Naijiria eyi ti wọn ni o n ta abuku ba àkọsílẹ̀ ijọba to wa lori aleefa pẹlu erongba rẹ lati mu ayipada ba eto ọrọ aje.

Ààrẹ Buhari ni oun ti ri iroyin kaakiri nipa àìtó owo tuntun naa ati ipa to n ni lori awọn oníṣòwò kekeke àtàwọn ọlọdani.

O ni ọjọ meje to ku ninu gbedeke ọjọ mẹwa ti wọn da ni awọn yoo fi lu ìṣòro to n da wahala aito owo tuntun naa silẹ ni ponpo.

Ki ni Aarẹ Buhari fẹ ṣe gangan?

"Maa kan si ile ifowopamo àpapọ̀ ati Ileeṣẹ to n tẹ owo.

A máa ṣe ipinu kan tabi omiran laarin ọjọ mẹwa ti wọn fi kun un, Ààrẹ sọ lọjọ Ẹti nigba to n ba awọn

Gomina sọrọ lọwọ pe “owo naa ti wọn yipada yoo mu ọrọ̀ aje buyari sii yoo si pese awọn anfani ọlọjọ pipẹ paapaa pẹlu ifarajin awọn banki si aṣeyọri aato naa”.

Ẹwẹ, aarẹ Buhari jẹ ko di mimọ pe awọn Banki kan ko koju osuwọn to lati ran aṣeyọri naa lọwọ.

“Awọn banki kan ko koju osunwọ, imọ tara ẹni nikan si ni wọn mọ, koda bi wọn ba fi gbedeke ọdun kan kun un, iṣoro imọtara ẹni nikan ati ọkanjuwa ko lee kuro nilẹ.”

Ẹwẹ, awọn Gomina sọ fun Aarẹ Buhari bo tilẹ jẹ pe awọn gba ipinu rẹ lori ayipada owo naa, awọn tun wa lẹyin rẹ bi ike, amọṣa awọn kan n fẹ ba iṣẹ rẹ jẹ ti awọn araalu ni agbegbe awọn kaakiri si ti n fi ehonu han.

Wọn wa sọ fun aarẹ pe gẹgẹ bi adari ijọba ati ẹgbẹ oṣelu ti awọn jẹ kaakiri ipinlẹ, ọkan awọn ti n lọ soke lori gbogbo wahala naa paapaa bi idibo ṣe n bọ lọna. Wọn wa rọ aarẹ lati lo agbara rẹ fi dari ọpọyanturu owo tuntun yii ati ti tẹlẹ titi di opin ọdun yii.

Aarẹ jẹ ko di mimọ pe tori wọn sunmọ awọn eeyan, oun ti gbọ igbe wọn, oun yoo si ṣiṣẹ lee lori.