Gómìnà Makinde so ètò ìpolongo ìbò rẹ̀ rọ̀ ná nítorí ọ̀wọ́ngógó Naira àti epo

Oríṣun àwòrán, Twitter/@seyiamakinde
Ọrọ ọwọngogo epo ati owo naira ti kan Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde naa bayii pẹlu bi o ṣe ti kede fifi eto ipolongo ibo rẹ rọ naa.
Gomina Makinde, gẹgẹ bi atẹjade kan ti kọmiṣọna fun eto iroyin nipinlẹ Ọyọ, Wasiu Ọlatubọsun ṣalaye pe igbesẹ naa waye gẹgẹ bi ara bi gomina naa ṣe n mọ riri ipenija ati inira ti ara ilu n ba pade pẹlu awọn eto ijọba to wa ni igboro lọwọ bayii pẹlu ayipada owo naira ati ọwọngogo owo ori epo.
Atẹjade naa tẹsiwaju lati ṣalaye lọjọ Ẹti ni gomina Makinde kede eyi nigba to n sọ pe ọpọ iya ati inira lo n koju araalu.
“Gẹgẹbi ara ami ọwọ to ni fun awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ, gomina ipinlẹ Ọyọ ti wa paṣẹ pe ki wọn so gbogbo eto ipolongo ibo lẹgbẹ oṣelu naa lẹkajẹka rọ naa.”
Ọrọ ọwọngogo epo ati owo naira ti mu kiipaya ati ikayasoke o waye kaakiri orilẹede naira pẹlu inira ti ọpọ n koju lori rẹ.










