Ilé-ẹjọ dajo ikú fún ọlọ́pàá méjì fún ẹ̀sùn ìpàníyàn

Oríṣun àwòrán, Others
Ile ẹjọ kan lorilẹ-ede Kenya ti dajọ iku fun ọlọpa ilẹ Kenya tẹleri fun ẹsun iṣeku pani gbajugbaja agbẹjọro ati ajafeto ọmọniyan kan ati awọn eeyan meji miiran ni nnkan bi ọdun mẹfa sẹyin.
Awọn ọlọpa meji miiran ati ara ilu kan ni awọn adajọ fun ni ẹwọn ọdun mọkandinlogoji si ọdun mẹẹẹdọgun fun pipa agbẹjọro Willie Kimani, alabara rẹ ati awakọ takisi kan ni Oṣu Karun ọdun 2016.
Awọn mẹrin ni ile ẹjọ fìdi re mulẹ lọdun to kọja wi pe ikọọkan won jẹbi ẹsun ipaniyan ati ẹsun meji miran.
Gbogbo awọn mẹrẹrin ni ile ẹjọ fun ni anfaani ọjọ mẹrinla lati pe idajọ naa lejo.
Ninu idajọ rẹ, Adajọ Jessie Lessit, sọ pe ẹri lakoko iwadii ti fihan pe wọn fiya jẹ Willie Kimani ati awọn ti wọn jo kowo rin ṣaju ki wọn to pa wọn.
Oku Willie Kimani, Josephat Mwendwa ati Joseph Muiuri ni wọn ri lẹyin ti wọn ti ju wọn sinu odo kan ni ẹkun odi olu-ilu naa, Nairobi.
Kimani ni oun gbejoro fun awakọ alupupu Josephat Mwenda ti o ti fi ẹsun kan ọlọpa Fredrick Leliman - ọkan ninu awọn ọlọpaa mẹta ti wọn jẹbi ẹsun ipaniyan pe o yibon fun u, laisi idi kankan lẹyin ti o daa duro ni opopona kan ni ọdun 2015.
‘’Kimani, Mwenda ati awakọ takisi wọn, Joseph Muiuri ni wọn ri gbeyin ni ọjọ kẹtalelogun osu kẹfa ọdun 2016 ni agọ ọlọpa kan.’’
‘’Ki a to ṣe awari ageku ẹya ara wọn lẹyin ọsẹ meji ninu odo kan ti o to ọgọrun kilomita si ilu Nairobi.’’















