Fídíò Tiktok gbé gbajúmọ̀ òṣèré dé ọgbà ẹ̀wọ̀n

Murja Ibrahin Kunya

Oríṣun àwòrán, Murja Ibrahin Kunya/Instagram

Ilé ẹjọ́ Sharia tó wà ní ìpínlẹ̀ Kano ti sọ arábìnrin kan tó jẹ́ gbajúgbajà tó ń ṣàmúlò Tiktok, Murja Ibrahim Kunya sí ẹ̀wọ̀n oṣù méjì.

Ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Murja ni pé ó ń kọ́ àwọn ènìyàn ní ohun tó lòdì sí Islam, tó sì tún ń dúnkokò mọ́ àwọn ènìyàn lórí ayélujára Tiktok.

Ní Ọjọ́bọ̀, Ọjọ́ Kejì, Oṣù Kejì, ọdún 2023 ni Murja kojú ìgbẹ́jọ́ nílé ẹjọ́ náà, èyí tí Abdullahi Haliru darí rẹ̀.

Ẹ̀sùn méjì ni wọ́n kà sí Murja lọ́rùn pé, ó ń dúnkokò láti ṣe ìkọlù sí àwọn kan àti pé ó tún fi àwọn fídíò kan tó lòdì sí òfin Islam sórí ayélujára.

Ilé ẹjọ́ ní àwọn fídíò ọ̀hún le ṣàkóbá fún àwọn ènìyàn mìíràn nítorí àwọn fídíò náà lòdì sí ìwà ọmọlúwàbí.

Ní ọjọ́ Àbámẹ́ta tó kọjá, lásìkò Murja ń ṣe ìpalẹ̀mọ́ ayẹyẹ ọjọ́ ìbí rẹ̀ tó ń bọ̀ lọ́nà, ni àwọn ọlọ́pàá nawọ́ gán-an wí pé , onírúurú ẹ̀sùn lórí àwọn fídíò tó ń fi sórí ayélujára ni ó ti kan àwọn lára.

Àwọn Alfa tí wọ́n ní Murja, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlélógún, ń lòdì sí òfin Islam àti ti ọmọlúwàbí ló mú ẹjọ́ rẹ̀ lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá.

Adájọ́ Abdullahi Haliru tó gbọ́ ẹjọ́ náà lọ́jọ́bọ̀ ní kí wọ́n ju òṣèré Kannywood tẹ́lẹ̀ rí náà sí ẹ̀wọ̀n ọ̀sẹ̀ méjì títí ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ yóò fi tẹ̀síwájú lọ́jọ́ Kẹrìndínlógún oṣù Kejì.

Misbahu Kofar Mata fìdí rẹ̀ múlẹ̀ fún BBC Pidgin pé Murja ti wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Kurmawa tó wà ní ìlú Kano.

Baba Jibo Ibrahim tó jẹ́ Agbẹnusọ ọgbà ẹ̀wọ̀n Kano ní ìgbẹ́jọ́ kò ì tíì bẹ̀rẹ̀, pé ó di ọjọ́ Kẹrìndínlógún tí adájọ́ mú kí ìgbẹ́jọ́ tó bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu.

Murja gbajúmọ̀ ní orí Tiktok fún irúfẹ́ àwọn nǹkan tó máa ń fi sórí ayélujára Tiktok, èyí tí ọ̀pọ̀ ènìyàn gbà pé ó yàtọ̀ sí nǹkan tí wọ́n mọ àwọn ènìyàn ẹkùn árẹ̀wá sí.

Ta ni Murja Ibrahim Kunya?

Agbègbè Hotoro ní ìlú Kano ni Murja ń gbé, tó sì jẹ́ gbajúmọ̀ lórí Tiktok.

Murja ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn fídíò tí òun máa ń fi sórí Tiktok ló yàtọ̀ sí ìwà òun gangan.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní òun parí ẹ̀kọ́ kewu, Murja kò parí ẹ̀kọ́ girama kó tó dáwọ́ dúró.

Ó bẹ̀rẹ̀ eré tíátà lábẹ́ Kannywood àmọ́ tó ní òun kò ní òkìkí nídìí iṣẹ́ náà gẹ́gẹ́ bí òun ṣe fẹ́.

Láti nǹkan bíi ọdún méjì báyìí ló ti gbajúmọ̀ lórí Tiktok fún àwọn fídíò tó máa ń fi síbẹ̀.