Jandor tó jẹ́ ayàwórán mí tẹ́lẹ̀, kò lé di Gómìnà Eko - Fashola

Aworan

Oríṣun àwòrán, Instagram.com/officialjandor/

Minisita feto irinna lorilẹede Naijiria, Babatunde Raji Fashola, ti sọko ọrọ si oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Eko, Abdulazeez Adediran, ti ọpọ mọ si Jandor.

Gomina tẹlẹ nipinlẹ Eko naa ni Jandor ko ni oye to peye lati tukọ eto iṣejọba ipinlẹ Eko, to si sapejuwe rẹ gẹgẹ bii ayaworan.

Fashola sọ eleyi nigba to n sọrọ nibi ifilọlẹ eto ipolongo ibo ẹgbẹrun mẹwaa eeyan fun oludije sipo aarẹ APC ati gomina ipinlẹ Eko.

Fashola sọ siwaju pe “Mo ṣe isẹ gomina fun ọdun mẹjọ.

Lara nnkan to ran mi lọwọ ni pe mo jẹ osisẹ agba fun ijọba, ki n to di gomina,

“Mo ti ni iriri sise akoso lati igba naa sugbọn ko to fun ipo akoso bii gomina, ki ni ka ti wa sọ ti eeyan to n tẹle gomina gẹgẹ bi ayaworan.

Ayaworan to n wo mi fun ọdun mẹjọ, o wa ro pe oun le di gomina? Ko ti ṣetan.

“O yẹ ko wa si ile ẹkọ wa lati wa ni imọ si nipa bi a ṣe n di olori, ko ti i ṣetan rara.

Nitori rẹ ni ẹ fi n ri awọn ipolongo ibo kan pe wọn gbajumọ gbigba owo bii aadọta biliọnu ti ipinlẹ Eko n pa wọle sugbọn wọn ko ṣọ bi awọn eeyan ṣe n wọle si ipinlẹ yii lati ibi gbogbo.”

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 1

Ẹrú PDP ló ń bá APC, ń kò sé ìsẹ̀ ayaworan rí - Jandor fèsì fún Fashola

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Oludije ẹgbẹ oṣelu PDP, Abdulazeez Adediran, ẹni to sisẹ ri ni ileeṣẹ iroyin ipinlẹ Eko, ti fesi pada fun Gomina tẹlẹ nipinlẹ Eko, Babajide Fashola.

Jandor ni pe o ti han gbangba pe ẹru ẹgbẹ oṣelu PDP n ba awọn ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Eko.

Jandor ni oun ko fi igba kankan jẹ ayaworan, to si pe awọn eeyan ipinlẹ Eko ati awọn ayaworan pe ki wọn forijin ọga oun tẹlẹ.

“A ni lati salaye awọn nnkan fun awọn araalu ti igbagbọ Ọga mi tẹlẹ ti si lọna.

Ko si nnkan to buru ninu pe ki eeyan jẹ ayaworan, ti mo si n tọrọ aforijin lọwọ awọn eeyan ipinlẹ Eko, paapa julọ awọn ayaworan, pe ki wọn forijin Ọga mi tẹlẹ fun ọrọ to sọ,

“N ko fi igba kankan jẹ Ayaworan ri. Isẹ ti mo ṣe pẹlu ileeṣẹ iroyin ipinlẹ Eko ko ni nnkan ṣe pẹlu yiya aworan rara.

“O da pe nnkan ti wa nibẹ pẹlu Ọga mi ati aworan.

Ti ẹ ko ba gbagbe, mo ranti pe Ọga mi lo ri ẹrọ ayaworan nigba ti isẹlẹ Endsars waye ni Lekki.

Jandor tẹsiwaju pe oun ko tabuku Ọga oun rara, koda, oun si ni apọnle fun gidi gan.

“A yo yọ ipinlẹ Eko kuro loko ẹru, Ọga mi Fashola yoo si kan sara si wa fun aṣeyọri nla yii.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 2