Ètò ìdóòlà ẹ̀mí níbi àjálù ilẹ̀ ríri ní Turkey, Syria kò ní pẹ́ wá sópin - Àjọ UN

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ajọ iṣọkan agbaye sọ pe eto idoola ẹmi ati kiko awọn oku kuro labẹ awoku ile latari ajalu ilẹ riri to waye ni orilẹede Turkey ati Syria ti n ṣe kẹrẹkẹrẹ sunmọ idawọ-duro.
Adari ẹka eto iranwọ fun iṣẹlẹ pajawiri lajọ iṣọkan agbaye, Martin Griffiths lo sọ eyi lasiko to fi n ba awọn akọroyin sọrọ nibi abẹwo rẹ si ilu Aleppo lẹkun ariwa orilẹede Syria.
O ni awọn igbesẹ bii ipese ileegbe, ounjẹ, ile ẹkọ ati itọju miran fun awọn to fara kaasa ajalu ilẹ riri naa lo kan bayii.
Ajọ UN gbajumọ ipese ohun eelo to yẹ fun itọju awọn to ye iṣẹlẹ ilẹ riri
O ni ohun to ku ti wọn fẹ gbajumọ bayii ni gbigbe igbesẹ to yẹ fun itọju awọn to ye iṣẹlẹ naa..
“Iporuru ọkan ti awọn eeyan wọnyi n la a kọja kọja afẹnusọ, gbogbo agbaye lo si nilo ati dide lati wo ọgbẹ wọn san.”
O ni ajọ UN yoo bẹrẹ si ni ko awọn ohun elo iranwọ kuro lati awọn agbegbe tawọn ọmọ ogun ijọba n ṣakoso lọ si awọn agbegbe iwọ oorun ariwa to wa ni ikawọ awọn ọmọ ogun ọlọtẹ lorilẹede Syria.
Eeyan to din diẹ lẹgbẹrun mẹrindinlogoji lo ti ku ninu ajalu ilẹ riri

Iye awọn to ku ninu ajalu ilẹ riri naa ti le ni ẹgbẹrun marundinlogoji (35, 000) bayii.
Awọn oṣiṣẹ ajọ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri lorilẹede Turkey n sọ pe ẹgbẹrun mọkanlelọgbọn ati ojilelẹgbẹta o le mẹta (31, 643) ẹmi lo ba ilẹ riri naa lọ nibẹ.
Awọn oṣiṣẹ ajọ iṣọkan agbaye, UN sọ pe iye awọn to ku lagbegbe iwọ oorun ariwa orilẹede Syria jẹ ẹgbẹrun mẹrin ati ọọdunrun, (4, 300).
Eyi mu ki apapọ iye awọn to ku jẹ ẹgbẹrun marundinlogoji ati ojilelẹẹdẹgbẹrun o le mẹta, (35, 943).
Ajọ iṣọkan agbaye n sọ pe akọsilẹ oku nibi iṣẹlẹ ilẹ riri lorilẹede Turkey ati Syria lẹyin o rẹyin lee wọ ilọpo meji iye yii.












