Ibadan Masquerade Festival: Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá ní ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀

Oríṣun àwòrán, others
Aarẹ ẹgbẹ awọn ọlọdẹ asọludẹrọ, Alhaji Nureni Ajijọla Anabi ti sọ pe awọn janduku lagbegbe Ọja igbo nilu Ibadan, ti ja ọdun eegun to n lọ lọwọ gba lagbegbe naa.
O ni awọn janduku naa ti sọ ọdun eegun di eyi ti wọn fi n pa eniyan bi ẹni n pẹran, ti wọn si tun n ṣe ọpọlọpọ eeyan leṣe.
AJijola Anabi sọ eyi ninu ifọrọwerọ pẹlu awọn oniroyin kan nilu Ibadan.
Gẹgẹ bi o ṣe sọ, ọdun egungun to n lọ lọwọ jakejado ilu Ibadan ti di ọdun wahala lagbegbe Ọja Igbo ati Ita Ẹgẹ.
- Ìjọba Oyo ti bẹ̀rẹ̀ sí ní kó àwọn oníbárà kúrò láàrin ìgboro ìlú Ibadan
- Fífẹ́ ọkùnrin ẹgbẹ́ mi jẹ́ ìgbésẹ̀ tó burú ju tí mo gbé láyé
- A ó sọ ibùdókọ̀ ojú irin ìlú Ibadan di gbàgede káràkátà láìpẹ́ - Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo
- Wo iye owó tí ìjọba Naijiria ti yá lọ́wọ́ China láti ìgbà tí Ààrẹ Muhammadu Buhari ti gorí àléfà
Gẹgẹ bi ohun to sọ fun awọn ileeṣẹ iroyin abẹle kan, Alhaji Nureni Ajijọla Anọbi ni awọn janduku lẹyin eegun naa pa eeyan kan, ti wọn si tun da ina sun ile rẹ.
Ọlọpaa ni ọrọ ko ri bẹẹ
Amọ ṣa, ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ ti sọ pe ko si ohun to jọ eyi ati pe, nirọwọ rọsẹ ni ọdun egungun ti ọdun yii n lọ nilu Ibadan.
Ninu atẹjade kan to fi ranṣẹ si BBC Yoruba, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọyọ, Adewale Osifeso ni awọn gbe eto ojulalakan fi n ṣọri ati ọtẹlẹmuyẹ kalẹ,
O ni awọn eto naa lo wa lati rii daju pe gbogbo ibi ti wahala lee ti fẹ suyọ ni wọn pa ina rẹ ko to ru.
O fi kun un pe, "gbogbo eleegun ni a ti ṣe ilanilọyẹ fun ṣaaju ọdun egungun naa, ti wọn si tun tọwọ bọwe adehun alaafia lati rii pe ko ni si rukerudo lasiko ọdun naa"
Ileeṣẹ ọlọpaa ni gbogbo igbesẹ ojulalakan fii ṣọri to yẹ ni awọn ti gbe, ki awọn janduku ma baa sọ ọdun egungun naa di ọdun idana ogun silẹ.


















