Yoruba Language: Ìran Yorùbá gbayì ní Austria
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
Ni ilu Salzburg orilẹede Austria, awọn omo Yorùbá para pọ̀ lati ṣe Ọdún Yorùbá.Ṣe ni awon ara ilu Austria gbaruku ti wọn, ko da wọn ba wọn kopa ninu iwọde t'ohun tilu tifọn to n ṣagbega ede ati aṣa Yoruba.
Egungun, Ẹyọ, Gẹlẹdẹ, ati bẹẹ bẹẹ lọ pelu awon nkan ara ti wọn fi hande nibi ọdun naa.Wọn tun da aso ebi paapa. Ṣe ni wan ń yọ bii ọjọ ti awn ankara wọn rẹwa jọjọ, ati Yoruba ati oyinbo lo yọ bi ọj ninu aṣọ ibilẹ Yoruba.Awọn ọmọ Yoruba agbegbe yii ko kan ko ara wọn jọ lati maa ṣe ohun to wu wọn nilẹ onilẹ, ijoba Austria naa fi ọwọ si i.


Orukọ wọn ni ẹgbẹ ọmọ̀ Oduduwa Salzburg Austria, ọdọọdun si ni wọn maa n ṣe ayẹyẹ Oduduwa pẹlu iwde aṣa kaakiri igboro ilu.
Awọn orin aṣa ati itan Yoruba, ijo ati gbigbe Egungun, Eyo ati Gelede kii gbẹyin.

Ọdun 2000 ni wọn ṣe iṣẹdalẹ Ẹgbẹ Ọmọ Oduduwa lati maa gbe aṣa Yoruba larugẹ, lati ri si mim'aye rrun fun awọn Yoruba to n gbe ni Austria ati mimọ ara ẹni fun idokoowo lagbaye.
Eto yii ti wa di ọkan lara eto ilu Salzburg lọdọọdun pẹlu ajọṣepọ ile iṣẹ to n ri si ọrọ aṣa ni Salzburg ti wọn maa n ṣagbatru ida to le ni marundinlọgọrin ẹnawo ayẹyẹ naa.










