EU: Òfo ni ètò ìdìbò 2019 ní Naijiria

Oríṣun àwòrán, Google
Ọpọlọpọ awuyewuye lo ti jẹyọ lori atẹjade ti Ajọ Ilẹ Yuroopu(European Union) fi lede nipa idibo ọdun 2019.
Ẹka to n se iwadii ni Ajọ Isọkan Yuroopu, EU EOM ni ofo ni idibo sipo aarẹ, ti ipo gomina ati si ile igbimọ asofin apapọ lorilẹede Naijiria.
Igbakeji Adari ẹka naa, Hannah roberts lo sọ bẹẹ lasiko to n ba awọn oniroyin jomitoro-ọrọ ni Abuja, olu ilu Naijiria.
Wọn jẹ ko di mimọ pe bi o tilẹ jẹ wi pe ajọ eleto idibo, INEC sọ pe iroyin naa waye ni irọwọ ohun irọsẹ.
Ṣugbọn iwadi ẹka ajọ EU naa fi han pe awọn kudiẹ kudiẹ ṣi wa ninu ilana eto idibo naa.

Oríṣun àwòrán, Google
Amọ, Ajọ EU ni awọn ko mọ nkankan nipa ẹrọ ‘server’ ti ẹgbẹ oselu PDP sọ wi pe Ajọ INEC fi ko esi idibo jọ lasiko idibo gbogboogbo to waye.











