Has JAMB registration been postponed: Wo ọjọ́ tí ìforúkọsílẹ̀ ìdánwò àṣewọlé JAMB yóò bẹ̀rẹ̀

JAMB

Oríṣun àwòrán, @KarmaPresh

Ajọ to n ri si idanwo aṣewọle iwe giga ni Naijiria, JAMB, ti kede pe iforukọsilẹ idanwọ aṣewọle si awọn awọn fasiti ọdun 2021 ko ni bẹrẹ lọjọ kẹjọ, oṣu Kẹrin yii.

Ninu ifọrọwerọ pẹlu agbẹnusọ ajọ naa, Fabian Benjamine, o ni JAMB ṣi n ṣe awọn eto kan lọwọ eyii ti ko jẹ ko ṣeeṣẹ lati bẹrẹ iforukọsilẹ naa lọjọ kẹjọ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ fun BBC, "ohun ti a ṣe ni pe, a gbero lati bẹrẹ iforukọsilẹ naa lọjọ kẹjọ, oṣu Kẹrin, ṣugbọn kii ṣe ikede ti a fi sita niyẹn."

Benjamine sọ pe ikede ti wọn ba fi lede nikan lo le sọ ni pato akoko ti iforukọsilẹ ọhun yoo bẹrẹ.

O fikun pe awọn n ṣe awọn eto kan lọwọ ti yoo mu ki iforukọsilẹ naa rọrun, awọn ko si tii pari rẹ.

Alukoro ajọ naa ṣo siwaju si pe lara awọn eto tuntun ti wọn ṣẹṣẹ fi kun iforukọsilẹ naa ni nọmba idanimọ NIN.

Àkọlé fídíò, Torí àti ṣe Kòkò irin, bí mo ṣe máa ǹ fara yá iná nìyìí - Amokoko Saki

O ṣalaye pe nọmba idanimọ NIN ọhun yoo mu ko rọrun fun awọn lati gba awọn alaye nipa awọn to fẹ ṣe idanwo naa lọwọ ijọba apapọ

O ni idi ree ti wọn ko tii ṣe bẹrẹ iforukọsilẹ naa, ki awọn to fẹ forukọsilẹ ma baa maa sa kiri nitori ọrọ NIN.

Nigba ti akọroyin BBC bere akoko ti iforukọsilẹ naa yoo bẹrẹ ni pato, o fesi pe "ọsẹ to n bọ ṣe pataki, ko si ohun ti yoo di wa lọwọ lati ma bẹrẹ lọsẹ to n bọ."

Àkọlé fídíò, 'Bí ojú ọ̀nà agbàrá òjò tí ijọba ṣe n'IIorin ṣe ń pa àwọn ọmọ iléèwé wa rèé! Ẹ sàánú wa'