Infidelity: Wo àwọn ọkùnrin méjì tí wọ́n ṣe pàṣípààrọ̀ ìyàwó wọn nítorí ìfẹ́

Oríṣun àwòrán, @Osmek
Iyalẹnu lo jẹ nigba ti iroyin gba ode kan lẹyin ti ọkunrin meji gba lati paarọ iyawo ara wọn nitori agbere ṣiṣe.
Awọn ọkunrin mejeeji ti ọṛọ kan, Arakunrin Josh Odour ati arakunrin Sakis wa lati ilu Busia ni orilẹede Kenya.
Awọn ọkunrin mejeeji yii lo paarọ iyawo ati awọn ọmọ wọn lẹyin ti Sakis ati iyawo Odour kede agbere ṣiṣe wọn si gbangba.
Gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin KDRTV ṣe gbe iroyin naa, Odour lo kọkọ gbọ pe iyawo rẹ n ṣe agbere pẹlu arakunrin Sakis, amọ ti ko gbagbọ.
- Ìjọba Naijiria kéde ọjọ́ Ìṣẹ́gun àti Ọjọ́rú tó n bọ̀ fún ìsinmi ọdún Ileya
- Akeredolu, NUJ àtàwọn míì ń ṣèdárò Bunmi Afuye tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ ìdigunjalè lọ l'Ondo
- Mọ̀ si nípa agbẹjọ́rò Yoruba Nation tó gbé Buhari lọ sílé ẹjọ́ àgbáyé ICC
- Ọwọ́ àjọ NDLEA tẹ ògbóǹtagì oníṣòwò òògùn olóró méje
- Àjọ̀dún odò Ẹ̀rìn, omi tí wọn kò gbọdọ̀ pa ẹja abàmì inú rẹ̀ wáyé nílùú Erinjiyan
- Ọmọ ìyá kan náà mẹ́ta kú lẹ́yìn tí wọ́n jẹ Àmàlà ní Ilorin
Amọ lẹyin naa lo tọpasẹ iyawo rẹ lọ si ile Sakis to siba a nibi to ti n fọ abọ.
Nibẹ ni iyawo rẹ ti sọ fun pe oun ti ko kuro nile lo ba arakunrin Sakis, eleyii to bi ọkọ rẹ ninu to si bẹrẹ sini dọrẹpọ pẹlu iyawo Sakis to ti kuro ninu ile fun wọn, to si lọ si ile awọn obi rẹ.
Iyawo Sakis gba lati ṣe Igbeyawo pẹlu Josh Odour , ti awọn mejeeji si sọ fun ileeṣẹ ọlọpaa nipa igbesẹ wọn.
Ninu ọrọ tirẹ, Odour ni oun ti ṣetan lati fun iyawo oun tuntun ni oyun lati le rọpọ awọn ọmọ mẹta to ti ni tẹlẹ, amọ ti wọn ti gba ni ọwọ rẹ.
O ni oun yoo tete ṣe eleyii nitori oun fẹran lati ma a ri ọmọ mẹta ninu ile.
Amọ o ni ẹni to gba iyawo oun yoo ni suuru diẹ ti wọn ba fẹ bimọ, nitori iyawo oun tẹlẹ ti ṣeto ifeto si ọmọ bibi ọlọjọ pipẹ si ara rẹ.















