Electoral act: Òfin ìdìbò tuntun, electoral act tún dá rúkèrúdò sílẹ̀ nílé aṣojú ṣòfin, ẹgbẹ́ alátakò bínú jáde

Ijoko ile asojusofin

Oríṣun àwòrán, House of representatives, FRN

Awọn aṣofinṣoju nile asofin apapọ orilẹede Naijiria tun bẹrẹ rukerudo lọjọ Ẹti ni gbagede ile naa lori agbeyẹwo ti wọn n ṣe lọwọ lori ofin tuntun ti wọn fẹ gbe kalẹ fun ajọ eleto idibo ilẹẹwa, INEC.

Lati Ọjọbọ lawọn aṣofin ti n gbe pẹrẹgi kana fun ara wọn laarin awọn to fọwọ si lilo imọ ẹrọ lati maa fi esi idibo ranṣẹ ati awọn to faramọ ki wọn maa lo ilana alafọwọko ti wọn n lo tẹlẹ.

Rukerudo to waye lori abala kejilelaadọta ti wọn n gbe yẹwo l'Ọjọbọ lo faa ti wọn fi gbe ijoko ile naa so rọ di ọjọ Ẹti.

Amọṣa, kaka ko san lara iya ajẹ awọn aṣofin apapọ naa lori rẹ, nṣe lo tun peleke pẹlu bi wọn tun ṣe tẹsiwaju pẹlu rukerudo naa lowurọ ọjọ Ẹti.

Ni kete ti Họnọrebu Idris Wase to n lewaju igbimọ apapọ ile to n gbe awọn abala ofin naa yẹwo lọkọọkan ni ile tun daru nigba to lu igi mọ aga pe awọn ti fẹnuko lori abala kejileldọta kan naa.

Eyi to mu ki ariwo ẹhonu sọ laarin awọn aṣofin to n pe fun idibo ori o jori lati yanju ọrọ naa.

Lẹyin ti agbeyẹwo naa de oju kan lawọn aṣofin lati ẹgbẹ oṣelu alatako, paapaajulọ PDP binu jade kuro nibi ijoko ile naa lọjọ Ẹti.