Almajiri: Kíni ìjọba ń ṣe lórí ewu ẹkọ Almajiri àti covid 19 ní Nàìjíríà?

Almajiri

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọrọ lori awọn ọmọ ile Kewu ni ariwa Naijiria ti ọpọ n pe ni almajiri ti pe fun apero ọmọ eriwo paapaa lasiko coronavirus to n tankalẹ bayii.

Awọn akọroyin BBC, Nduka Orjinmo ati Mansur Abubakar se agbeyẹwo ohun to n sẹlẹ pẹlu bi awọn kan ni ariwa Naijiria ti se pe fun iwọgile eto ẹkọ almajiri.

Eyi kò ṣẹyin bi ọpọ awọn ọmọ almajiri ṣe n di dida pada laarin ipinlẹ ariwa Naijira kan si ikeji lẹyin ti niinu wọn lugbadi ajakalẹ arun Coronavirus

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin ni ariwa?

Laipẹ yi ni awọn ọkọ akero bẹrẹ si ni ko ẹgbẹẹgbẹrun awọn ọmọ ile Keu almajiri lati awọn ipinlẹ ti wọn wa ni agbegbe ariwa Naijiria pada lọ si ilu ti wọn ti wa ni ọrọ n bẹyin yọ.

Lootọ ni ijọba fofin de igbokegbodo awọn ọkọ sugbọn wọn faaye silẹ fawọn ọkọ lati ko awọn ọmọ naa lọ si abule ibi ti wọn ti fiwọn ransẹ sọdọ awọn Aafa ile kewu to n kọ wọn ni kewu.

Lawọn ipinlẹ mọkandinlogun to wa ni ariwa Naijiria, bi awọn ọmọ kan ba ti se n lọ lawọn miran n bọ ti wọn n kiri lati ipinlẹ kan si ikeji lorukọ Almajiri.

Almajiri

Oríṣun àwòrán, jigawa

Ko si ẹni to le sọ pato iye awọn ọmọ kewu yi ti wọn fi n ransẹ sugbọn ipinlẹ Kaduna nikan sọ pe ẹgbẹrun lọna ọgbọn awọn ọmọ yi lawọn da pada si ipinlẹ wọn.

Ki ni o fa igbesẹ ka maa fi ọmọ ransẹ silu wọn pada lasiko Coronavirus?

e awọn alasẹ to fọwọ si idapada awọn ọmọ wọnyi si ipinlẹ ti wọn ti wa mọ wipe awọn n dakun itankalẹ arun Covid 19 ni?

Eyi ati awọn ibeere miran ni ọpọ ọmọ Naijiria n beere bayii lọwọ awọn gomina ipinlẹ Ariwa ti wọn ti kọkọ n ṣatilẹyin fun aṣa Almajiri tẹlẹ.

Àkọlé fídíò, What causes coronavirus: Akeugbagold sọ àṣírí ohun ti àrùn coronavirus ń dá lárá f

'Ewu nla ti awọn alasẹ kọti ikun si'

Iwadii awọn akọroyin BBC fihan pe bi awọn ọmọ wọ yi ti se n pada si ipinlẹ wọn, ni awọn alasẹ n se ayẹwo ti wọn si n ya wọn sọtọ.

Esi to tẹyin ayẹwo yi wa mu ki awọn eeyan faraya.

Ni ipinlẹ Kaduna, ninu awọn mọkandinlaadọsan ti wọn yẹwo, maarundinlaadọrin ni arun naa.

Ọrọ ko yatọ ni Jigawa ti awọn mọkanlelaadọrun ni arun naa ninu awọn mejidinlaadọsan.

Ni Gombe, mẹjọ ninu awọn mejidinlaadọta ni arun naa, ti Bauchi, awọn meje ninu mejidinlogoji ni arun naa.

Ọrọ yi buso sini lẹnu to tun bu yọ sii bayii ti onikaluku ti n da ọmu iya rẹ gbe nitori itankalẹ arun coronavirus.

Boss Mustapha to jẹ olori igbimọ to n gbogun ti arun Covid-19 ni Naijiria ni ọpọ igba ni ijọba ti kilọ fun awọn Gomina ariwa Naijiria sugbọn wọn keti ikun si ikilọ awọn.

Lọkan awọn Gomina wọnyi, anfaani lati da awọn ọmọ yii pada si ipinlẹ wọn lo de yi,

Awọn kan gba pe dida wọn pada yoo jẹ ọna lati koju ipenija eto ẹkọ alimajiri ti wọn ti fẹ wọgile tipẹ ni ariwa Naijiria tawọn musulumi pọ si.

Àkọlé fídíò, Coronavirus: Opó afọ́jú kan sọ̀rọ̀ lórí ìnira tó ń kojú pẹ̀lúu coronavirus

Awọn Gomina ariwa Naijiria wo lo ṣe lodi sii aṣa ẹkọ kewu Alumajiri?

Almajiri

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọkan pataki lara awọn to n pariwo lodi si alumajiri ni Emir atijọ fun ipinlẹ Kano ti Gomina Ganduje rọ loye, Lamido Sanusi Lamido.

Enikeji ni Gomina Kaduna Nasir El Rufai to n tukọ ipinloẹ Kaduna bayii.

El Rufai sọ pe awọn ti n wọna lati pa eto alimajiri yi rẹ.

Ninu ọrọ rẹ, o ni o san ki awọn ijọba fun awọn ọmọ yi ni ẹkọ iwe igbalode ju ki wọn ma rin kaakiri titi.

El Rufai ni : ''Ni Kaduna, eto ẹkọ alimajiri ko tun ni gberi mọ nitori a ṣe lodi sii bayii'

Àkọlé fídíò, Coronavirus: BBC News Yorùbá ní kí ẹ dúró nílé bí ẹ kò bá ní ìdí láti jáde

Tani awọn ọmọ Almajiri gan an?

Awọn ọmọ almijari yi lawọn ọmọ to wa lati idile ti o ku diẹ kaato fun lawujọ.

Wọn a maa lọ si ọdọ Aafaa tabi Mallam ti yoo kọ wọn ni kewu fun bi ọdun marun un si mẹwaa.

Pupọ ninu wọn ko ni ribi kọ kewu ọhun ti wọn a si maa tọrọ bara loju titi kaakiri.

Ajọ UNICEF sọ pe o fẹ to awọn ọmọ miliọnu mẹwaa le diẹ to wa laarin ọdun marun un si mẹrinla ti ko si nile iwe ni Naijiria.

Awọn ọmọ alimajiri ti a n wi yii lo pọju ninu wọn.

Almajiri

Oríṣun àwòrán, @muhammed

Ki lo mu kawọn ọmọ yi maa tọrọ bara fun owo kiri titi?

Pupọ ninu awọn Mallam to gba awọn ọmọ yi sọdọ ni ko rọwọmu lọ si ẹnu funra wọn to jẹ pe ko si owo pupọ lọwọ wọn lati gbe igbeaye to pe.

Nigba ti ipa wọn ko ka itọju awọn ọmọ yi ti awọn obi wọn ko si ni owo ti wọn yoo fun wọn, igba bara lọpọ maa n gbe lati le fi ri ounjẹ jẹ.

Awọn Mallam to ba n dako a maa fi awọn ọmọ yi sisẹ ninu oko wọn.

Àkọlé fídíò, Olutoye: Ọmọ ọdọ̀ àgbà ni mí, kò sì y kí èdè Yorùbá parun

Ko si owo kankan ti wọn maa n san fawọn ọmọ to n sisẹ sin wọnyi

Kini Ohun ti ẹsin Islam sọ nipa imọtoto:

  • Idaji ẹsin ni imọtoto jẹ
  • Ki o to jẹun tabi ti o ba jẹun tan, o gbọdọ fọwọ rẹ
  • Bi o ba se igbọnsẹ, o di dandan ko fọwọ
  • Ọwọ fifọ, oju ati ẹsẹ gbodo waye ki eeyan to ki irun lẹẹmarun un lojumọ
  • Iwẹ di ọranyan ki eeyan to ki irun akojọpọ Jimọ ni gbogbo ọjọ Eti
  • Bi eeyan ba salaisi, wọn gbọdọ wẹ oku, awọn onimọ ẹsin kan ni ko se dandan ti ko ba si anfaani lati se bẹẹ

Kini ero ijọba bayii?

Ijọba kede pe ki wọn ti awọn ile kewu almajiri pa ni ipari osu Kẹta sugbọn nitori pe awọn ọmọ yi ko nii ri ibi kankan lọ, wọn si n tọrọ bara loju titi.

Nigba ti awọn Gomina ri ohun to n sẹlẹ ti ẹru si ba wọn pe awọn ọmọ yi le ko arun yii, ni wọn ba pinnu lati da awọn alumajiri pada si ilu wọn. Sugbọn aṣọ ko ba Omọyẹ mọ.

Ko si ẹni to le sọ bi awọn ọmọ yi ti se ko arun yi sugbọn ko lee sẹyin bi wọn ti se n gba bara kiri lati ojule kan si ekeji.

Ki lawọn onimọ ẹsin atawọn obi ọmọ Almajiri sọ?

Almajiri

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Nigba ti i a bi awọn onimọ ẹsin bi i : Sheikh Abdullahi Garangamawa, imaamu mọsalasi Jafar Adam ni Kano; o ni awọn eeyan ti sọ eto ẹkọ alimajiri di idakuda.

O ni eto ẹkọ alimajiri to wa lode bayi ko yatọ si ki wọn maa mu awọn ọmọ yi sin bi ẹru.

''Ọpọ awọn ọmọ yi lo ti di janduku fawọn oloselu nitori wọn ko kọ kewu tawọn obi wọn ran wọn lati lọ kẹ''

Sugbọn kii se gbogbo eeyan lo lero bi tirẹ.

Awọn obi kan bi Shafiu Yau ni awọn ko fẹ ki wọn wọgile eto alimajiri.

O sọ fun BBC pe ọmọ oun ọdun mẹẹdogun wa nile kewu alimajiri ni Kano.

''Ọdun keji re to n lo lọwọ. Ka to wi ka to fọ, yoo pari ẹkọ rẹ ti yoo si mọ nipa Quran ati ẹsin Islamu daadaa''

Àkọlé fídíò, Kí ni ìtumọ̀ àwọn alárùn covid-19 tí wọ́n ń pè ní ''Asymptomatic'' ?

Awọn olori Naijiria ti n jaran nkan ti wọn le se si eto ẹkọ yi lọjọ to ti pẹ.

Ọrọ naa jẹ eleyi to fẹ le diẹ nitori pe awọn musulumi lo pọju lariwa Naijiria ti awọn to gbe lẹyin eto ẹkọ yi si ni ọna ati pa ẹkọ Islamu lara ni ijọba fẹ da.

Lasiko Goodluck Jonathan to sejọba saaju aarẹ Buhari, o na ọpọlọpọ biliọnu owo naira lati kọ awọn ile ẹkọ almajiri

Amọ, Aarẹ Buhari to wa lori oye yi ti sọ pe oun fẹ ki wọn wọgile iru ẹkọ yi ki wọn si ko awọn ọmọ almajiri lọ si awọn ile ẹkọ ti wọn kọ labẹ ijọba Jonathan sabẹ akoso ijọba ati awọn onimọ ẹsin.

Bi a ti se n sọrọ yi, awọn ile ẹkọ wọnyi ti di ahoro ti awọn akẹkọọ si ti tuka pada soju titi nibi ti wọn ti n tọrọ bara.

Ibeere nla to wa nilẹ bayi ni pé: ki wa ni ijọba le se lati dẹkun ipenija Almajiri paapaa julọ lasiko ajakalẹ arun Covid-19 yi?

Àkọlé fídíò, Abẹ́rẹ́ àjẹsára nítorí covid-19