LASU Ritual: Àwọn akẹẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ LASU tí wọn fi ṣowó sọ̀rọ̀ lórí ìgbé ayé olóògbé

Àkọlé fídíò, LASU Ritual: Àwọn akẹẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ LASU tí wọn fi ṣowó sọ̀rọ̀ lórí ìgbé ayé olóògbé

Awọn ẹbi, ara, ọrẹ ati akẹkọọ fasiti LASU lo peju si itẹ oku Atan loni lati sin oku Favour Daley-Oladele, ti iya, ọmọ pẹlu Pasitọ sekupa lati fi se oogun owo.

Ṣugbọn fun iyalẹnu wọn, eto isinku naa ko lee waye nitori bi ijọba ipinlẹ Eko, lati ipasẹ ileesẹ eto ilera se kọ lati gbe oku naa silẹ.

Nigba to n sọrọ lori isẹlẹ naa fun BBC Yoruba, ẹgbọn oloogbe naa, Toyome Solomon parọwa si gbogbo ẹbi ati ọrẹ oloogbe lati bomi suuru mu ki iwadi gidi lee waye.

O wa fi ọwọ idaniloju sọya pe ọga ọlọpa nipinlẹ Eko yoo sisẹ bo se yẹlati ri pe idajọ ododo waye lori iku to pa Favour.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa, awọn akẹẹgbẹ oloogbe naa meji, to wa lati fasiti LASU, Oluwatobi Olowu ni iku Favour ba awọ̀n lojiji, ti wọn si tun se alaye iru eeyan ti akẹkọbinrin naa jẹ nigba aye rẹ.