''Àìsí ìṣọ̀kan láàrin Afenifere kò le ṣe àkóbá ìbò fún Tinubu''

Oríṣun àwòrán, Other
Onimọ nipa eto oṣelu, to tun jẹ olukọ ni Fasiti Ibadan, Ọjọgbọn Dikrullahi Yagboyaju ti sọ pe nkan ayọ lo jẹ fun Bola Ahmed Tinubu, bi ẹgbẹ́ Afenifere ṣe buwọlu.
Ọjọ Aiku ni eekan ẹgbẹ́ ọmọ Yoruba, Afenifere, Pa Reuben Fasoranti ati awọn agba ilẹ̀ Yoruba kan, buwọlu oludije ẹgbẹ́ oṣelu All Progressives Congress, si ipo aarẹ, Bola Tinubu.
Ọjọgbọn Yagboyaju sọ pe Oríṣiríṣi itumọ to jinlẹ ni bibuwọ lu ẹni to ba n dije fun ipo oṣelu, nitori pe bi oludije ba ṣe ni alatilẹyin si, nie anfaani rẹ lati de ipo.
"Olúdíje kankan ko gbọdọ ni ọ̀tá kankan" ninu irinajo rẹ.
Ọjọgbọn Yagboyaju sọ pe bi Afenifere labẹ idari Pa Fasoranti ṣe kede atilẹyin wọn fun Tinubu, jẹ oriire fun, ati fun agbo oṣelu Naijiria.
O ni ireti oun ni pe igbeṣẹ Afenifere yoo tàn de àwọn agbegbe to ku ni Naijiria, paapaa ni awọn ẹ̀yà to pọ, lati buwọlu idije Tinubu.
O ni nkan ti eyi tumọ si ni pé, to ba fi di aarẹ, wọn o ni le pe e ni aarẹ ẹ̀yà kan ṣoṣo.
Ẹnikẹ́ni to ba tako ikede Fasoranti, ni ẹtọ lati ṣe bẹẹ - Onwoye
Lori bi awọn ọmọ ẹgbẹ́ Afenifere ko se fi ẹnu kò lori oludije kan naa, Ọjọgbọn Yagboyaju sọ pe oun ko lero pe yoo ni ipa buruku lara Bola Tinubu.
Ṣáájú ni agba ninu ẹgbẹ́ naa, to tun jẹ alaga ẹgbẹ́, Oloye Ayo Adebanjo, kede pe oludije fun ipo aarẹ lati inu ẹgbẹ́ oṣelu Labour Party, Peter Obi, ni Afenifere yàn.
Koda, ko si nibi ipade ti Tinubu ṣe pẹlu awọn àgbà ẹgbẹ́ ọhún n'ilu Akure.
Onimọ eto oṣelu, Ọjọgbọn Dikrullahi Yagboyaju sọ pe ẹnikẹ́ni to ba tako ikede Fasoranti, ni ẹtọ lati ṣe bẹẹ.
" Ṣugbọn nkan ti a rí ti Fasoranti ṣe, paapaa bi awọn agbaagba ilẹ Yoruba ṣe wa nibi eto naa fihan pe imọ wọn ṣọkan."















