Èèyàn 35 ní ọkọ mí kó lọ ṣiṣẹ́ ní Ikoyi, méjì péré ló padà - Opó

Àkọlé fídíò, Ikoyi Collapsed Building: Bíríkìlà tó yè lábẹ́ ilé tó wó ní kò sí agbára láti ṣiṣẹ́ mọ́
Èèyàn 35 ní ọkọ mí kó lọ ṣiṣẹ́ ní Ikoyi, méjì péré ló padà - Opó

N kò ní okun láti ṣiṣẹ́ mọ́, aya mi ti kó lọ - Bíríkílà

Oni ọjọ Isẹgun, ọjọ Kinni osu Kọkanla ọdun 2022 lo pe ọdun kan gbako ti isẹlẹ ile alaja mọkanlelogun to da wo ni Ikoyi waye.

Ọpọ ẹmi si lo ba isẹlẹ ile to dawo naa lọ nigba naa, ti wọn si ri eeyan diẹ yọ laaye labẹ awoku ile ọhun.

Adugbo Gerrard ni Ikoyi nilu Eko si ni isẹlẹ naa ti waye, ti iye eeyan to si wa lori ile to wo naa to aadọta niye.

Nibayi ti isẹlẹ ibi ọhun ti pe ọdun kan gbako, BBC Yoruba se awari awọn mọlẹbi awọn osisẹ to ba isẹlẹ naa lọ lati mọ bi igbe aye wọn ti ri lẹyin ọdun kan ti eeyan wọn papoda.

Bakan naa la tun ba ọkan lara awọn eeyan ti ori ko yọ lara awọn eeyan to ha sabẹ ile naa lasiko isẹlẹ ọhun sọ ipo ailera ti wọn wa fun BBC Yoruba.

Awọn bi alaisi atawọn tori ko yọ

“Ninu eeyan marundinlogoji ti ọkọ mi ko lọ sisẹ nibi ile to da wo ni Ikoyi, meji pere lo pada wa sile”

Ọpọlọpọ awọn opo alaisi ti ọkọ wọn ba isẹlẹ ile Ikoyi to da wo lulẹ ni Ikoyi lọ, lo salaye fun BBC Yoruba pe nnkan ko rọgbọ lati igba ti baale wọn ti jade laye.

Wọn ni jijẹ, mimu di wahala, ti oju mẹrin to n tọ awọn ọmọ, to wa di oju meji ko si jẹ ki nnkan fararọ.

Omiran ninu wọn tiẹ sọ pe awọn ẹbi ọkọ awọn ko beere awọn wo lati igba to ti jade laye, ti bukata si wọ awọn lọrun.

Bakan naa ni ọkan ninu wọn sọ pe Baba Onile tawọn n gbe ti le oun ati awọn ọmọ kuro nile nigba to nira lati sanwo ile.

O ni awọsun ni oun n se kaakiri pẹlu awọn ọmọ oloogbe, eyi to nira pupọ.

Obinrin kan ninu awọn opo naa tiẹ tara poro pe ninu awọn osisẹ marundinlogoji ti ọkọ oun ko lọ sisẹ nibi ile to da wo lulẹ naa.

O salaye pe aye nira fun idile oun lati gbe lati igba naa, ti oun ba si mọ ni, oun ko ba ti jẹ ki ọkọ oun lọ sisẹ lọjọ naa nibi ile to dawo lulẹ ni Ikoyi.

Àkọlé fídíò, Ikoyi Collapsed Building: Bí ilé alájà mọ̀kànlélógún ṣe dà wó lulẹ̀ ní Ikoyi, l‘Eko rèé

“Ara wa ko lokun mọ lati sisẹ lati igba ta ti ha sabẹ ile to dawo ni Ikoyi, koda, aya ti salọ”

Meji lara eeyan meji to ye ninu isẹlẹ ile to wo lulẹ ni Ikoyi naa, ti ori ko wọn yọ ninu eeyan marundinlogoji to tẹle ọkọ opo kan lọ, naa ba BBC Yoruba sọrọ nipa iriri rẹ.

Awọn ọkunrin naa, ti irisi rẹ fihan pe ara wọn ko dape, lo salaye pe ilera awọn ko ti dape lati igba ti awọn ti ha sabẹ awoku ile alaja mọkanlelogun naa ni Ikoyi.

Wọn ni koda, awọn ko tii le sisẹ kankan lati pawo wọle lati igba ti isẹlẹ naa ti waye, awọn eeyan si lo n saanu awọn lati ri ọwọ mu lọ sẹnu.

Ọkan ninu wọn tiẹ sọ pe lẹyin isẹlẹ naa ni iyawo oun ko lọ, to si fi oun silẹ.

Wọn wa n bẹbẹ fun iranwọ, ki adinku le ba aini to n bawọn finra.

“O yẹ ki ẹni to n kọle seto adojutofo fun ile atawọn osisẹ tori isẹlẹ pajawiri bii eyi”

Gbolahan Oke, tii se ọga agba ni ẹka to wa fun amojuto ile kikọ nilu Eko naa ba BBC Yoruba lori iya tawọn eeyan to fori sọta isẹlẹ ile to dawo naa n jẹ.

Oke ni pe kii se ojuse ijọba ni lati sanwo adojutofo fawọn to ba ni ijamba nidi ile kikọ.

O salaye pe o yẹ ki ẹni to ba n kọle seto adojutofo lori ile to n kọ tori iru ajalu ile didawo tabi isẹlẹ ibi miran.

Bakan naa lo ni o yẹ ki ẹni to ni ile naa tun seto adojutodo fawọn osisẹ to n ba sisẹ ile kikọ naa nitori ijamba.

O fikun pe owo yii ni wọn yoo ri gba bii owo gba ma binu lẹyin ti ijamba ba waye lasiko ti wọn n sisẹ ile kikọ na lọwọ.

Bawo ni ile alaja mọkalelogun se dawo ni Ikoyi lọdun kan sẹyin?

Ọjọ nla ni ọjọ Aje, ọjọ kinni osu Kọkanla ọdun 2021 ti ile alaja mọkanlelogun da wo lulẹ ni ojule Kẹrinlelogun, opopona Gerard ladugbo Ikoyi nilu Eko.

Eeyan to le ni aadọta lo wa ninu ile ti wọn n kọ lọwọ naa, nigba to fi da wo lulẹ ni ojiji, to si pa ọpọlọpọ awọn eeyan to wa ninu ile naa.

Lara awọn to ba isẹlẹ ile to da wo lulẹ naa lọ ni ẹni to ni ile naa, Enginia Femi Osibona tii se oludasilẹ ileesẹ abanikọle Fourscore to gbajugbaja fun ile kikọ nilẹ yii ati loke okun.

Bakan naa ni ọrẹ timọtimọ Osibona, Wale Bob-Oseni, to wa lati oke okun, to ya ki ọrẹ rẹ nibi ile naa, ba isẹlẹ naa lọ, tori awọn mejeeji ni ile ọhun jọ wo pa.

Bakan naa ni ọpọ birikila atawọn osisẹ miran to n sisẹ lọwọ lara ile naa jade laye, ti ẹtahoro eeyan to ha sabẹ awoku ile naa, ti wọn yọ jade laaye si di alaabọ ara.

Ẹni to ba de ibi ti ile ti da wo lulẹ ni Ikoyi lọkan kan sẹyin, to ba jẹ ori ahun, yoo sunkun.

Bi o tilẹ jẹ pe ko sẹni to le sọ ohun to se okunfa ile didawo naa lasiko ti isẹlẹ naa waye amọ ọpọ iwadi npa isẹlẹ naa ti n jade sita.

Gẹgẹ bi iwadi ijọba ti wi, ailakasi awọn ileesẹ ijọba to n fontẹ lu ile kikọ ati amojuto ile lo sokunfa isẹlẹ ibi yii.