Jàǹdùkú yawọ ilé Abẹnugan ilé aṣòfin US, bí wọ́n ṣe fọ́ "hammer" mọ́ ọkọ rẹ̀ lórí rèé

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ara ọkọ Abẹnugan ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà, Paul Pelosi ti ń balẹ̀ lẹ́yìn tó ṣiṣẹ́ abẹ látàrí ọgbẹ́ tó fara gbà nígbà tí ẹnìkan ṣe ìkọlù sí i nílé wọn ní San Francisco.
Afurasí tó ṣe ìkọlù náà ló fi hámà gbá Pelosi, ẹni ọdún méjìlélọ́gọ́rin lórí tó sì tún ṣèṣe lọ́wọ́.
Ìkọlù sí ilé Abẹnugan Nancy Pelosi yìí ló ti ń fa ìbẹ̀rùbojo sọ́kàn àwọn ènìyàn orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà bí wọ́n ṣe ń gbáradì fún ìdìbò tí yóò wáyé lọ́jọ́ kẹjọ oṣù kọkànlá ọdún yìí.
Afurasí ọ̀hún, David Depape ni wọ́n ní ó bèèrè láti rí Nancy Pelosi nígbà tó dé ilé wọn ṣùgbọ́n tí onítọ̀hún kò sí nílé lásìkò ìkọlù náà.
Ààrẹ Amẹ́ríkà, Joe Biden ti bu ẹnu àtẹ́ lu ìkọlù yìí tó sì ní kò sí ààyè fún ìwà ọ̀daràn lásìkò tí ètò òṣèlú bá ń lọ.
Biden tó sọ̀rọ̀ ní Philadelphia ní gbogbo àwọn gbọ́dọ̀ sowọ́pọ̀ láti gbógun ti ìwà jàǹdùkú nínú ètò òṣèlú lai fi ti ẹgbẹ́ òṣèlú kankan ṣe.
Lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ tí ìkọlù náà wáyé ni ìjọba Amẹ́ríkà kọ̀wé ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn agbófinró orílẹ̀ èdè wọn láti ṣe ìkìlọ̀ nípa àwọn ìkọlù tó ń wáyé sáwọn tó ń dupò òṣèlú àti àwọn òṣìṣẹ́ ètò ìdìbò.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀ láti mọ ìdí tí afurasí náà fi fẹ́ ṣekúpa Pelosi ṣùgbọ́n wọn ò tíì fìdí rẹ̀ múlẹ̀.
Báwo ni ọwọ́ Ọlọ́pàá ṣe bá afurasí?
Nancy Pelosi tó wà ní Washington DC lásìkò tí ìkọlù ọ̀hún wáyé ti balẹ̀ sí San Francisco láti wá wo ọkọ rẹ̀ ní ilé ìwòsàn.
Agbẹnusọ Pelosi ní òwúrọ̀ ọjọ́ Ẹtì ni afurasí náà ṣe ìkọlù ọ̀hún nígbà tó fi tipátipá wọ ilé wọn tó sì ń bèèrè láti rí Abẹnugan.
Ọ̀gá Ọlọ́pàá San Francisco, Chief William Scott ní nǹkan bíi ago méjì òru òwúrọ̀ ọjọ́ Ẹtì ni àwọn gba ìpè láti ọ̀dọ̀ Pelosi.
Scott ní nígbà tí àwọn ọlọ́pàá máa fi débẹ̀, níṣe ni àwọn bá afurasí ọ̀hún àti Pelosi tí wọ́n ń jà sí hámà ṣùgbọ́n tó ti fi hámà náà ṣe Pelosi léṣe.
Ó ní èròńgbà afurasí náà ni láti so Pelosi títí tí ìyàwó rẹ̀, Nancy yóò fi padà sílé.
Ó fi kun un pé ẹ̀sùn fífi ipá wọ ilé onílé àti àwọn ẹ̀sùn mìíràn ló ń kojú.
Bákan náà ló ní afurasí ọ̀hún wà ní ilé ìwòsàn níbi tó ti ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́ ṣùgbọ́n kò sọ bí ìlera afurasí náà ṣe wà sí.
Scott ṣàlàyé pé Pelosi ló fọgbọ́n pe àgọ́ Ọlọ́pàá láti lè jẹ́ kí àwọn gbọ́ bí ìkọlù náà ṣe ń wáyé.
Ta ni Nancy Pelosi?
Ní ọdún 2021 ni wọ́n dìbò yan Nancy Pelosi bí i Abẹnugan ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin fún ìgbà kẹrin.
Láti ọdún 1987 ni Nancy Pelosi tó jẹ́ ọmọ ìlú Baltimore ti ń ṣojú ẹkùn San Francisco ní ilé aṣòfin orílẹ̀ èdè náà.
Àárín California àti Washington DC ló máa ń gbé jù àmọ́ San Francisco ni ọkọ rẹ̀ ń gbé.
Ní ọdún 1963 ni wọ́n fẹ́ ara wọn, tí wọ́n sì bí ọmọ márùn-ún.
Láti oṣù kìíní ọdún 2021 ni àwọn aṣòfin ọ̀hún tí ń kojú ìpèníjà ààbò lẹ́yìn ìkọlù tó wáyé sí US Capitol.















