Wo bi o ṣe lè wo orúkọ rẹ nínú àkọsílẹ̀ olùdìbò tí INEC gbé jáde

Akọsilẹ orukọ oludibo

Oríṣun àwòrán, inec

Ajọ eleto idibo ni Naijiria, INEC, ti bẹrẹ si ni lẹ iwe orukọ awọn oludibo kaakiri.

Eto naa yoo waye larin ọjọ kejila, oṣu Kọkanla titi di ọjọ kejidinlogun, oṣu Kọkanla ọdun 2022.

Ajọ INEC sọ pe lilẹ awọn orukọ naa lasiko yii, wa ni ibamu pẹlu abala kẹsan-an ati ikọkandinlogun ofin eto idibo.

Igbesẹ yii n waye lati le fun awọn oludibo to fi orukọ silẹ ni anfaani lati mọ boya orukọ wọn wa nibẹ tabi ko si i.

Wọn o tun le fi to INEC leti, ti wọn ba ri orukọ ẹni ti ko yẹ lati dibo, amọ ti orukọ rẹ wa lori iwe tabi to ti kú.

Bi eto naa yoo ṣe waye:

INEC yoo lẹ orukọ awọn oludibo lati ọdun 2011 titi di 2022, ni awọn wọọdu idibo kọọkan, olu ileeṣẹ ajọ naa ni ijọba ibilẹ, ati awọn olu ileeṣẹ rẹ ni agbegbe nla jakejado Naijiria.

Awọn oṣiṣẹ ajọ naa, pẹlu iranlọwọ awọn agunbanirọ ni yoo mojuto eto orukọ naa ni wọọdu

Awọn alamojuto idibo si ni yoo ma a dari wọn

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Ọna lati wo orukọ rẹ lori ayelujara

Yatọ si awọn orukọ ti INEC yoo lẹ̀ si awọn wọọdu idibo, o tun ni anfaani lati yẹ orukọ rẹ wo lori ayelujara.

  • Lọ si itakun agbaye INEC
  • Yan ipinlẹ rẹ ati wọọdu rẹ
  • Lẹyin naa, wa a yan ibudo idibo rẹ, ki o si tẹ ‘display’. Orukọ gbogbo oludibo ni ibudo idibo naa yoo jade fun ọ lati ri.