Busuyi Ayowole Adedeji, ẹni ọdún 38 tó fẹ́ jẹ Gomìnà Ìpínlẹ̀ Osun

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Busuyi Ayowole Adedeji tí ọ̀pọ̀ mọ sì BSY jẹ Onimọẹro and Oloṣelu orile-ede Naijiria ti o jẹ olujide sipo gomina ni Ipinlẹ Osun labe asia ẹgbẹ oselu People's Redemption Party
Ọdun 1984 ni wọn BSY, tí ó sì jẹ ọmọ bibi ìlú Iléṣà ni Ipinlẹ Osun, ọdun yìí lo pe ọmọ ọdun mejidinlogoji.
BSY bẹrẹ ile iwe alakobere ni The Apostolic Primary School ni Igbogi-Ikoyi, lẹyin naa ni o darapo mọ Rosemary Nursery and Primary School àti Nawarudeen Primary School.
BSY parí ilé iwe grammar ni osu keje ọdun 2001 lẹyin darapo mọ ilé ìwé mẹta otooto fun Ile iwe grammar; Methodist High School, Obokun High School, ati Ogedengbe Commercial High School.
Methodist High School, ó sun siwaju lọ sí Obokun High School atiOgedengbe Commercial High School ni Ipinlẹ Osun.
Lẹyin ti o jade ni ile iwe grammar, Ayowole mu orile fasiti Obafemi Awolowo niluu ile ife láti gba 'Diploma' nínú 'Computer Technology' lọdun 2002.
O tẹsiwaju lọ sí Federal University of Technology, Akure ni bi tí o ti kawe gba oye 'Bachelor Degree' ninu Mechanical Engineering lọdun 2009.
Ni afikun, BSY tẹsiwaju lati gba imo oye 'Master Degree' ninu Design and Production Engineering láti Fasiti ipinlẹ Eko.
Busuyi Ayowole darapo oṣelu lọdun 2019 lẹyin ti o dibo sipo Sẹneto tí o soju ila Orun ipinlẹ Osun labe asia ẹgbẹ oselu People's Redemption Party.
BSY jẹ ọkan lara awọn ọdọ tí ó jade lati dibo sipo Gomina Ipinlẹ Osun















