'Ó ń ṣe mi bíi kí n tètè parí sáà mi... Wo àwọn ǹkan tí Buhari ti sọ rí pé òun yóò máa ṣe lẹ́yìn sáà òun

Àwòrán aarẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, others

Ọpọlọpọ ọrọ ni o ti jade lati ẹnu Aarẹ Muhammadu Buhari nipa bi yoo ti ṣe gbe ile aiye rẹ ni ti o ba ti pari saa rẹ lọdun 2023.

Lọdun 2015 , Buhari kede dukia rẹ fun awọn ọmọ orilẹde Naijiria, ti o si jẹ Aarẹ akoko lorilẹde Naijiria to kede awọn dukia fun araye pẹlu igbakeji rẹ, Ojọgbon Yemi Osibajo leyin ti wọn jawe olubori ninu eto idibo ti wọn ti koju Aarẹ ana, Ọmọwe Goodluck Jonathan .

Aarẹ kede pe oun ni ile gbigbe marun-un, ile amọ meji, ọgba fun orisirisi ohun ẹso, Maalu toto mẹtadinlọgọrin o le nigba. Aguntan mẹẹdọgbọn, Ẹsin marun-un ati ọrisirisi ẹya ẹyẹ to n fo ati to n rin.

Buhari tun ni oun ni ipin ninu awọn ilessẹ mẹta ọtọtọ, ilẹ meji ati ọkọ ayẹkélẹ mejii.

Ọdun keje ti Aarẹ ti n ṣe isakoso orilẹde yii ni sugbọn Aarẹ kede laipẹ pe oun ti fi oju sọna lati pari saa rẹ nitori ẹto ilera rẹ.

Aarẹ Buhari sọ pe kete ti oun ba ti pari saa oun, isẹ agbẹ ti oun pa ti nigba ti oun fẹ jẹ aarẹ ni oun yoo pada si lẹyin ọdun 2023.

Aworan aarẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, others

Ọrọ yii lo jade lẹnu Aarẹ nigbati o ṣe ayẹyẹ ọjọbi ọdun mọkandinlọgọrin lo oke pẹ.

Aarẹ ni ẹni ti o ni oko ni ilu rẹ to wa ni Daura, ni ipinlẹ Katsina.

“Mo n fi oju sọna si ọdun 2023 ti n ba pari saa mi, mo fẹ pada sile lati lọ mojuto oko mi.”

Ko tan sibe, Aarẹ Muhammadu Buhari tun ni oun ko ni fi ogun kankan silẹ fun ẹnikẹni lati jogun ati pe ohun ti o jẹ oun logun ju ni ẹko fun awọn ọmọ oun.

Buhari so eleyi nigba ti o ṣe abẹwo ikini ku ọdun si Emir ti ilu Daura, Dr Faruk Umar Faruk ni aafin rẹ.

“Awọn ọmọ mi ti mọ pe n ko ní fi nnkankan silẹ fun ẹnikẹni lati jogun. Ohun to jẹ mi logun ju ni lati rii pe awọn ọmọ mi ri eto ẹkọ to peye.”

“Afojusun mi ni lati rii pe awọn ọmọde ri iwulo wọn nibikibi ti wọn ba ti ba ara wọn.

aworan aarẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, others