Gbogbo ìletò, wọ́ọ̀dù ni Ọlọpàá ti wà digbí! Àwọn ojú Ọlọ́pàá tẹ́ẹ kò mọ̀ ní Osun yóò mú ẹni tó bá tasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀

Alukoro ile iṣẹ Ọlọpa Naijiria, Olumuyiwa Adejobi ti fi ogun ileeṣẹ Ọlọpaa Naijiria gbari pe wọn ti ṣe gudugudu meje yaaya mẹfa lati rii pe idibo ipinlẹ Osun waye ni alafia ni ipinlẹ Osun.
O ni ọga awọn patapata ti yan awọn ọga nla ninu iṣẹ wọn to tun jẹ ọmọ Yoruba lati iha guusu iyẹn ilẹ Yoruba ti oun funra rẹ jẹ ọkan lara wọn ki wọn lọ ṣiṣẹ ni Osun.


Koda o ni Ọga agba mẹrin lati ilu Abuja naa wa nikalẹ to fi mọ awọn Kọmisọna Ọlọpaa lati rii pe gbogbo igbesẹ ti ileeṣẹ Ọlọpaa ba gbe ni Osun yoo dantọ ti ẹnikẹni ko ni ri aidaa kankan mu ninu iṣẹ wọn.












