Biafra at 50: Àwòrán mánigbàgbé nípa ogun abẹ́lé Nàíjíríà

Ọjọbọ, Ọjọ Kẹẹdogun, osu Kinni, ọdun 2020 lo pe aadọta ọdun ti ogun abẹle ni Naijiria wa sopin eyi ta n se iranti rẹ.

Ohun ija oloro pẹlu awọn ọmọogun Nigeria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aye n lọ, a n tọọ. Ẹ́ wo ohun ija ti wọn fi ja ogun abẹle ni aadọta ọdun sẹyin. Arugbo soge ri ni
Awọn eeyan to di ẹru lati sa kuro ni ilu wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Bi ilẹ yii ko ba se e gbe, a lọ gbe ilẹ miran lawọn eeyan ti ogun abẹle ka mọle n sọ nilẹ Ibo
Ile ti wọn kọ tawọn ọmọ ogun bajẹ lasiko ogun Biafra

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, O ma se o. Ile yii ni wọn kọ lasiko ogun abẹle Biafra, to si wo lasiko ogun abẹle naa
Ọmọogun kan ko ru ibọn mẹrin sori

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Haba! Ki lo le to eyi, Eeyan kan ibọn mẹrin. Orukọ wo la ba fun akọni ologun yii
Awọn ọmọ ologun
Àkọlé àwòrán, Haa, Ẹ wo awọn akọni ologun to ja ogun abẹle ni aadọta ọdun sẹyin. Ọpọ wọn yoo ti di baba agba lasiko yii
Obinrin ti awọn ọmọogun de ni okun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ki wa ni obinrin yii lee se to fi n jẹ iru iya bayii? Apa ọwọ rẹ yii, se o lee jinna bi? Nitori ogun Biafra a lọ tabi a ko lọ yii naa ni
Iya kan gbe oku ọmọde lọwọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọlọrun ma jẹ ki abiyamọ fi oju sunkun ọmọ, ọmọde kan ree to ba ogun abẹle lọ
Awọn to n ta ọti lasiko ogun abẹle

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ohun to n pa oloko lẹkun, ni aparo awọn eeyan kan fi n se ẹrin rin. Nibi ti ogun ti n waye lawọn agbegbe kan, lawọn kan n fi ọti se faaji nibomiran
Ọkunrin kan gbe iya arugbo kuro ninu ile to wo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ado oloro lo wo ile mọ iya yii lori lasiko ogun abẹle, haa, oju ma ri to o
Awọn ibọn aloku lasiko ogun abẹle

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Oluwa oo, aduru ibọn yii ni wọn fi ja ogun abẹle! Se ilu ko ti run bayii?
Ologun kan to fi ara gbọgbẹ ni wọn gbe kuro loju ogun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọpọ awọn ologun to jẹ alaabọ ara ilu to wa nigboro, ni wọn ti fi ẹmi wọn lelẹ fun isọkan Naijiria nigbakan ri bii ti ọkunrin yii
Awọn ologun to gbe ibọn lọwọ n fo fayọ pe ogun abẹle ti wa sopin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ija pari, ọtẹ buse, a dupẹ ogun pari. Orin yii ni awọn ologun yii mu bọnu lẹyin ti wọn kede pe ogun abẹle ti wa sopin lọdun 1970