Ìdí tí a ṣe ṣàfikún owó okọ̀ BRT ni pé a kò tíì ṣetán láti kógbá wọle - Fola Tinubu

BRT

Oríṣun àwòrán, @wotzupNG

    • Author, Olumide Owaduge
    • Role, BBC Yoruba, Lagos

Ileeṣẹ Primero Transport Services Limited to n mojuto ọkọ akero BRT ni ipinlẹ Eko ti sọ pe idi ti ileeṣẹ naa ṣe ṣafinkun owo ọkọ BRT lasiko yii ni pe ileeṣẹ naa ko jere

Oludari ileeṣẹ ọhun, Fola Tinubu sọ fun BBC ninu ifọrọrọwerọ kan pe ileeṣẹ naa ko jere tẹlẹ ki igbele Coronavirus to bẹrẹ, nkan tun buru si lẹyin igbele.

Tinubu ni "Iye owo kan naa ni a ra epo ati awọn ohun elo ara ọkọ bi taya atawọn nnkan mii."

O tẹsiwaju pe oke okun ni ileeṣẹ naa ti n ko awọn ohun elo ara ọkọ BRT naa wa si Naijiria, koda o ni miliọnu kan dọla ni wọn fi ra ohun elo ara ọkọ ọhun laipẹ yii.

Oludari ileeṣẹ naa ṣalaye pe ko sẹni to n ro boya ileeṣẹ ọhun n jere, ṣugbọn o dabi pe ẹkunwo nikan ni awọn eeyan n ri.

BRT

Oríṣun àwòrán, @InsideMainland

Ṣaaju ni ijọba ipinlẹ Eko ti ni ki ọkọ BRT maṣe ko ju ogun eeyan lọna ati tẹlẹ ilana itaketesiraẹni ti ajọ eleto ilera gbe kalẹ niroti Coronavirus.

Àkọlé fídíò, Kayeefi: Òtítọ́ àti irọ́ wo ló wà nípa oògun owó àtàwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kàyééfì míràn

Ni bayii, Tinubu ti ni ileeṣẹ naa yo bẹrẹ si n ko eeyan ogoji ero pẹlu ẹkunwo tuntun ọhun.

Ni ti awọn ilana ti ileeṣẹ naa gbe kalẹ lati dabo bo awọn ero inu ọkọ rẹ lasiko Coronavirus yii, Tinubu sọ pe ileeṣẹ naa yoo pese "hand sanitizer" fun awọn ero ọkọ naa ti wọn ba ti n wọle.

O ni "A ko ni tan ero amuletutu to wa ninu ọkọ ọhun ati pe a oo ri daju pe gbogbo ero inu ọkọ wa lo wọ ibomu."

O fi kun pe afikun tuntun naa ko ṣeyin ijọba ipinlẹ Eko.

Bo tilẹ jẹ pe o ni afikun naa yoo ni awọn eeyan lara lasiko yii, Tinubu sọ pe ojuṣe oun ni lati ri pe ileeṣẹ naa ko kogba wọle ati pe o si n pa owo.mọ.

Àkọlé fídíò, Ṣé ọ̀rọ̀ yìí ò wa tóbi jù láti túmọ̀ sí Yorùbá?