Mothers Day: Adebunmi Adeyeye ní òun jẹ gbèsè gbọ́múléláńtà, ìdí iṣẹ́ kabúkabú ni òun ti ri san
Laye ode oni, o dabi ẹnipe ko si ohun ti awọn ọkunrin n se, ti awọn obinrin ko le se daa ju tọkunrin lọ.
Obinrin kan ree to wọ inu isẹ awakọ ta mọ mọ awọn ọkunrin tẹlẹ lọ, to si n wa ọkọ kabukabu.
Adebunmi Adeyeye, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ salaye pe, asọ ọkunrin ni oun n ta tẹlẹ amọ oun ko ri owo tawọn onibara jẹ oun gba pada lẹyin igbele Coronavirus.
O ni oun jẹ gbese san diẹ diẹ, ta mọ si owo gbọmulelanta, idi si ree ti oun fi gba idi isẹ awakọ lọ, nibi ti oun ti ri owo naa san.
Bakan naa lo tun salaye fun BBC Yoruba nipa awọn iriri to da omi tutu si lọkan nidi isẹ kabukabu naa sugbọn ti ko tori awọn iriri naa, fi isẹ ọhun silẹ.
Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ǹjẹ́ o mọ àwọn òṣèré bí Oyin Adejọbi, Funmi Martins àtàwọn míì tó ti dágbére fáyé?
- Ìtàn ìgbé ayé Isola Ogunsola 'I-sho Pepper', ògbóǹtagí òṣèré tíátà tó s'eré Yorùbá yíká Nàìjíríà
- Kí ló wà ní ìdí igbá tí àwọn olorì Aláàfin máa ń tí lóde Ọ̀yọ̀
- Ìjà Awolowo, Akintola àti ogun 'Wẹtiẹ', ẹ̀kọ́ wo ló kọ́ wa?
- Igbo Olodumare rèé, níbi tí Ìgbín ti tóbi ju Ìjàpá lọ
- Ìdílé márùn-ún tó gbajúmọ̀ fún òwò ẹrú nílẹ̀ Yorùbá
- Wo ìtàn ayé gbajúmọ̀ adigunjalè méje nílẹ̀ Yorùbá
- Mo di afọ́jú lẹ́yìn oṣù mẹ́ta tí aya mi kú lọ́jọ́ ìkúnlẹ̀ - Wòlíì Oluwalogbon
Adeyeye, tii se iya ọlọmọ kan ti ko ni ọkọ, wa gba awọn obinrin akẹẹgbẹ rẹ nimọran lati dawọle gbogbo isẹ to ba wa ni arọwọto wọn, eyi to le mu owo wọle fun wọn, yatọ si isẹ asẹwo.



