Ìpènijà márùn ún tí yóò kojú olóòtú ìjọba tuntun ní UK

Lizz Truss

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọjọ kẹfa, oṣu Kẹsan an, ọdun 2022 yii ni wọn burawọle fun olootu ijọba tuntun ni UK, iyẹn Liz Truss.

Iburawọle naa lo waye lẹyin ti wọn ti kọkọ dibo yan ninu ẹgbẹ oṣelu Conservative.

Truss ni obinrin kẹta ninu itan ilẹ Gẹẹsi ti yoo di ipo naa mu lẹyin Margaret Thatcher ati Theresa May.

Amọ ṣa, bo tilẹ jẹ pe ọpọ eeyan kaakiri agbaye lo ti bẹrẹ si n ki Truss ku oriire ipo tuntun naa, oniruru ipenija ni olootu ijọba tuntun ọhun jogun ba.

Awọn ipenija marun un ti Liz Truss to gba ipo lẹyin Boris Johnson yoo koju ree

Akọkọ ni ipenija ọwọngogo ounjẹ atawọn nnkan mii to gbode kaakiri agbaye, lọwọ yii.

Iye owo ti wọn n ra gaasi ati ina ijọba ti gbowo lori ni UK gẹgẹ bo ṣe wa lawọn orilẹ-ede mii kaakiri agbaye.

Ekeji ni eto ọrọ aje to dẹnukọlẹ, awọn onimọ ti sọ pe eto ọrọ aje ilẹ Gẹẹsi ko ṣe daadaa bii ti atẹyinwa bo tilẹ jẹ pe ọpọ awọn eeyan kaakiri agbaye lo n tẹkọ leti si orilẹ-ede ọhun.

Ipenija kẹta ni igbesẹ Britian lati kuro lara Eruope, iyẹn Brexit, eyii ti wọn ko tii yanju.

Bo tilẹ jẹ pe wọn ti n ṣe aṣeyọri igbesẹ naa, awọn nnkankan wa ti wọn ko tii yanju bii ala ilẹ laarin rẹ ati Northern Ireland, eyii to jẹ ara ilẹ UK ati Republic of Ireland ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ European Union.

Ipenija kẹrin ni bi awọn awakọ atawọn oṣiṣẹ ọkọ oju irin ṣe da isẹ silẹ laarin ọdun yii.

Gẹgẹ bii ohun ti awọn onimọ sọ, ipenijna karun un ni ipinya to n waye lọwọlọwọ ninu ẹgbẹ oṣẹlu Conservative, ti Liz Truss funra rẹ ti wa.

Ki lo ti sẹlẹ ṣaaju?

Wo ohun mẹ́wàá pàtàkì nípa Luz Truss, Olóòtú ìjọba UK tuntun

Lizz Truss

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọjọ Aje, ọjọ karun un, oṣu Kẹsan an, ọdun 2022 yii ni wọn kede Liz Truss gẹgẹ bii olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi tuntun.

Ikede naa waye lẹyi ti Truss jawe olubori ninu dibo awọn adari ẹgbẹ oṣelu Conservative.

Truss ni apapọ ibo 81,326 lati fidi alatako rẹ, Rishi Sunak to ni apapọ ibo 60,399 janlẹ.

Ni bayii, Truss ni yoo joko sori aga Boris Johnson to kọwe fi ipo naa silẹ ninu oṣu Keje ọdun yii.

Awọn ohun to yẹ ki o mọ nipa olootu ijọba UK tuntun naa ree

  • Orukọ abisọ rẹ ni Mary Elizabeth Truss
  • Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu keje, ọdun 1975 ni wọn bi obinrin naa ni Oxford, nilẹ Gẹẹsi, sinu idile John Kenneth ati Priscilla Mary Truss
  • Truss kẹkọọ nipa imọ Imoye, Iselu ati Ọrọ aje ni nile ẹkọ Merton College, ni Oxford, o si kawe gboye lọdun 1996
  • Ọdun 1996 ni Truss darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu Conservative nibi to ti bẹrẹ irinajo rẹ gẹgẹ bii oloṣelu
  • Oun ni akọwe ijọba fun ọrọ okeere ati idagbasoke titi di igba to di olootu ijọba
  • Ọjọ kẹwaa, oṣu Karun un, ọdun 2010 lo di ọmọ ile igbimọ aṣofin ilẹ Gẹẹsi
  • Truss ti kọkọ dije du ipo nigba meji ọtọtọ lọdun 1998 ati 2001 amọ o lulẹ
  • O ti ṣiṣẹ ni oniruru ẹka ijọba ilẹ Gẹẹsi gẹgẹ bii akọwe
  • Obinrin naa ni olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi kẹrindinlọgọta ati obinrin kẹta ti yoo di ipo naa mu lẹyin Margaret Thatcher ati Theresa May