Aṣọ́bodè gba èròjà olóró tówó rẹ̀ tó N33.3m àti aṣọ̀ ológun lọ́nà Ijebu Ode

Aworan

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ileeṣẹ aṣọbode ni Naijiria ti ni awọn n ṣiṣẹ takun takun lọna ati koju eto aabo to mẹhẹ, paapaa awọn to n ko eru wọle si Naijiria ni ọna ẹburu.

Adari ẹka ileeṣẹ naa ni ipinlẹ Eko, Hussein Ejibunu ni awọn ri garawa oogun oloro Carbide ti wọn fi n ṣe ado oloro to le ni ogun, ti wọn fẹ gbe yọ wọ Naijiria.

Ejibunu ni opopona Abeokuta si Ijebu-Ode ni ọwọ awọn ti tẹ awọn to gbe oogun oloro ni ipinlẹ Ogun.

O ni apapọ owo kabaidi naa to miliọnu mẹtalelọgbọn naira o le diẹ (N33.3m)

Bakan naa lo ni awon oṣiṣẹ wọn ri awọn ti wọn n yọ gbe aṣọ awọn sọja wọle, ki wọn to ra wọn gba.

Ninu ọrọ rẹ, o ni awọn to n ko ẹru lorisirisi wọ Naijiria peleke si nitori asiko ọdun to n sun mọ ile.

Amọ o ni awọn n gbiyanju lati fi ọwọ ofin mu wọn.

‘’Gbogbo igba la n ṣe ayẹwo awọn nkan ti awọn eniyan n ko wọle.’’

‘’Paapaa awọn to n ko oogun oloro wọle, awọn miran ko ki n san owo ori ti wọn ko wọle, gbogbo rẹ ni a n bojuto.’’

‘’Lori garawa oogun oloro ogun ti a ri ko, iru nkan bayii lee da alaafia orilẹede ru.’’

Nitori ti awọn ohun ija oloro yii ba kan eniyan lara, o le e ṣe ijamba fun ẹmi ati dukia awọn eniyan.’’

A ko tilẹ gbọdọ fi aye gba awọn ẹni ibi lati ko iru nkan bayii wọ orilẹede Naijria nitori to ba kan omi, ewu nla ni.’’

Ti eniyan ba fi ọwọ kan oogun oloro Calcium Carbide abi ko mi si imu, o le e da aisan si agọ ara eniyan, ọna ọfun ati bẹẹ bẹẹ lọ.

‘’Lara agbegbe ti ati ri awọn ẹru jibiti ti wọn fẹ ko wọle gba ni Idi-Roko, Ọyọ, Seme, Ijẹbu Ode ati awọn ibukodo oju omi.’'