Ìdí rèé táwọn ibùdó ìfọpò kò fi lè ṣiṣẹ́ mọ́ bí ìjọba àwaarawa kò ṣe pé wa l'Áfíríkà - Obasanjo

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ orilẹede Naijiria tẹlẹri, Oloye Olusegun Obasanjo naa ti sọrọ lori bawọn ologun ṣe n gbajọba kaakiri ilẹ Afirika.
Obasanjo sọ oju abẹ n’iko nigba ti o sọ pe eto ijọba awaarawa ti Afirika n wo awokọṣe rẹ lati ilẹ okeere ko le ṣiṣẹ fun ilẹ Afirika.
Aarẹ Naijiria tẹlẹ ri ṣalaye pe awọn orilẹede awọn oyinbo ti wọn n lo irufẹ eto oṣelu awaarawa ti a n lo lọwọ yii ti goke agba.
Bakan naa ni o sọ pe awọn orilẹede alawọfufu yii ko ni iru iṣoro tawọn orilẹede Afirika n doju kọ.
Obasanjo ni ‘’ilẹ Afirika ni lati joko ki wọn si ronu irufẹ ọna ati iṣejọba ti yoo bawọn eeyan lara mu.
A ni lati fori kori ki a si fẹnu ko lori irufẹ iṣejọba to lo ṣiṣẹ fun wa l’Afirika.
Ti a ba ṣe akiyesi, mẹta ninu awọn orilẹede mẹfa tawọn ologun ti gbajọba ni wahala wọn bẹrẹ lẹyin ti eto idibo waye tan.
"Awọn ologun to n gbajọba ni Afirika ko lero lati gbe ijọba pada fun alagbada mọ"
Ta lo le lọ sọ fun mi orilẹede Afirika tawọn eeyan ti n ri ẹtọ wọn gba ninu ijọba awaarawa?’’
Obasanjo ni awọn ologun to n gbajọba ni Afirika ko tiẹ lero lati gbe ijọba pada fun alagbada mọ.
‘’Mo ṣe akiyesi pe awọn ọdọ n gbaruku ti wọn, wọn si fẹ wa lori aleefa awọn ati iran diran wọn ni.
Mo ranti igba ti mo lọ si orilẹede Guinea lẹyin ti Ọgagun Mamady Doumbouya gbajọba Aarẹ Alpha Condé.
Ọgagun to gbajọba yii ko tiẹ fẹ ri mi rara, ko yọju si mi ti mo fi kuro nibẹ tori ko mọ ohun ti mo fẹ sọ,’’Obasanjo ṣalaye.
''Idi ree ti ileeṣẹ ifọpo Naijiria ko fi le ṣiṣẹ''
Obasanjo tun ṣalaye pe ileeṣẹ ifọpo mẹrin orilẹede Naijiria ko le ṣiṣẹ laelae niwọn igba to ba jẹ pe ijọba lo si n se akoso rẹ.
Aarẹ Naijiria tẹlẹri sọ pe oun sọ fun ileeṣẹ epo rọbi Shell lati maa ṣakoso awọn ileeṣẹ ifọpo mẹẹrin Naijria.
Obasanjo ni Shell ko gba lati ṣe bẹẹ tori pe iwa ajẹbanu ti pọju lawọn ileeṣẹ ifọpo Naijiria.
‘’Lẹyin igba naa ni Aliko Dangote ati Femi Otedola san owo to din diẹ ni miliọnu lọna ẹgbẹrin owo dọla lati ra ipin idaji ninu ileeṣẹ ifọpo to wa ni Port Harcourt ati Kaduna.
Amọ, o ṣe ni laanu pe Umaru Yar’Adua fagile adehun yii, o si da awọn ileeṣẹ ifọpo naa pada sọwọ NNPC.
Ṣugbọn mo sọ fun wọn pe ileeṣẹ ifọpo Naijiria ko le ṣiṣẹ niwọn igba to ba jẹ pe ijọba lo n ṣakoso rẹ.















