Òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn wọ gàù lẹ́yìn tí ìwádìí BBC sàfihàn bí ó ṣé tá ọmọ ìkòkò

Oríṣun àwòrán, BRIAN INGANGA/ BBC
Oṣiṣẹ ile iwosan kan lorilẹede Kenya ti iwadi BBC ṣafihan bi o ṣe ta ọmọ ikoko ni ọja okunkun ti wa ni ahamọ fun ẹsun tita ọmọ.
Fred Leparan, ẹni to n ṣiṣẹ nile iwosan kan ni Nairobi, Lucy Kibaki, ni fọnran rẹ jade lasiko to n tẹwọgba owo to to $2,050 lati ta ọmọ ikoko to wa labẹ itọju ile iwosan naa.
Ọwọ tẹ ẹ lọdun 2020 lẹyin ti iwadi ẹka iroyin ọtẹlẹmuyẹ BBC, Africa Eye jade.
Leparan pẹlu oṣiṣẹ kan lati ile iwosan miiran, Selina Awour ni wọn fẹsun naa kan.
Ẹsun mẹta ni wọn ka si Awuor lọrun ti wọn si da a lare lori ẹsun tita ọmọ ikoko.
Awọn mejeeji yoo gbọ idajọ wọn lọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kẹsan an.
Bawo ni iwadi ṣe waye?
Akọroyin Iwadi BBC Africa Eye lọ ba Leparan to si n ba a sọrọ bii pe o fẹ ra ọmọ ikoko lọwọ rẹ lẹyin naa a rii gbọ pe pe osisẹ ile iwosan kan wa n kun un lọwọ ninu tita ọmọ ikoko ni ile iwosan ijọba.
Wọn ṣeto ipade ni ile iwosan naa, nibi ti Leparan ti bẹrẹ, akọroyin BBC, to ni oun ati ọkọ rẹ ni ipenija lati bimọ, ti wọn si jiroro ko to wa gba lati ta ọmọ fun un.
Lọjọ ti wọn da lati gbe ọmọ naa lati ile iwosan lọ si ile iwosan ijọba, pẹlu awọn ọmọ meji mii, Leparan ni wọn ya fọnran bi o ṣe yi iwe pada fun awọn ọmọ naa.
BBC ri daju pe awọn ọmọ mẹtẹẹta ni ja silẹ si ile awọn ọmọ ikoko sugbọn wọn ya fọnran Laparan bi o ṣe yi iwe pada to si pe awọn onibara pe ọmọ naa ti di ti wọn lati gbe lọ.
Pẹlu gbogbo ẹri to wa nilẹ, ẹjọ ọhun ni wọn ti fa lati bi ọdun meji bayii. Leparan ni o ni anfani lati gba agbẹjọro to da julọ ni Kenya sugbọn ohun ti ẹlẹri sọ ko lọ deede.
Leparan yari kanlẹ pe oun kọ ni oun wa ninu iwadi ti BBC, to si ni ẹlomii lo ni ohun to wa ninu fọnran naa
Nigba to ya, Leparan ni awọn kan wa to jẹ ti tohun.












