Dókítà gbàgbé irinṣẹ́ sínú obìnrin kan fún ọdún kan àbọ̀ lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ ìbímọ

Aworan Ile Iwosan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn dokita onisẹ abẹ gbagbe ọkan lara irinsẹ wọn to tobi bi abọ ounjẹ sinu obinrin kan niluu New Zealand lẹyin to fi isẹ abẹ bimọ nile iwosan kan ni Auckland.

Irinsẹ ọhun ti orukọ n jẹ ‘Alexis wound retractor’ ti wọn ma fi wo egbo, lo wa ninu obinrin yii fun oṣu mejidinlogun lẹyin to bimọ.

Ninu oṣu meji yii, inu inira ni obinrin yii wa, to si n parọ ile iwosan kaakiri, ki wọn to ṣe ayewo fun un.

Awọn ajafẹtọ ẹni sọ pe ile iwosan naa jẹbi arabinrin yii.

Saaju ni olori ile iwosan naa, Te Whatu Ora Auckland, ti n jiyan pe irọ ni ati pe itọju to peye ni awọn fun obinrin naa.

Kọmisana fun eto ilera ni igba keji ree ti awọn dokita yii yoo gbagbe irinsẹ sinu obinrin ni ile iwosan Auckland.

“Ẹri to wa lọwọ wa safihan itọju ti wọn pese fun obinrin naa lo kudiẹ kato, ti wọn ko si ayẹwo to yẹ to jẹ pe ohun lo fa ti wọn fi gbagbe irinsẹ sinu obinrin naa

“Awọn osisẹ to wa ni bi isẹ abẹ naa ko ri nnkan sọ pato bi wọn ṣe gbagbe irinsẹ ati bi wọn ko ṣe fura pe irinsẹ wa ninu obinrin naa.”

Kọmisana fun eto ilera ni igba keji ree ti awọn dokita yii yoo gbagbe irinsẹ sinu obinrin ni ile iwosan Auckland.

“O yẹ ki ile iwosan yii ni ilana ti wọn tẹle”, eyi ni gbolohun Ms McDowell.

Aworan Irinsẹ ‘Alexis wound retractor’

Oríṣun àwòrán, APPLIED MEDICAL

"Mo gba pe isẹlẹ yii ti da wahala si ni agọ ara obinrin yii, to si ko oun pẹlu mọlẹbi rẹ sinu rogbodiyan"

“Inira buruku ni obinrin yii la kọja fun ọjọ pipẹ, ki wọn to yọ irinsẹ naa ninu ọdun 2021.

Mo gba pe isẹlẹ yii ti da wahala si ni agọ ara obinrin yii, to si ko oun pẹlu mọlẹbi rẹ sinu rogbodiyan.

Wọn ko darakọ obinrin naa lati dabo bo.

Ile iwosan ti wa tọrọ aforijin lọwọp obinrin naa, ti wọn fi n da awọn araalu loje pe ilera wọn lo jẹ wọn logun.

“A n fi da araalu loju pe irufẹ isẹlẹ yii sọwọn, ti a n si fi dayin loju pe awọn akọsẹmọsẹ ni akoju.’

Awọn agbẹjọro ti bẹrẹ si ni gbe ọrọ naa yẹwo boya ki wọn gbe lọm si ileẹjọ.