Kò yẹ kí ilé ẹjọ́ dá sí ọ̀rọ̀ "ta ló borí nínú idibo", ẹ̀ ń tẹ ẹ̀tọ́ àwọn olùdìbò lójú mọ́lẹ̀ - Bode George

Aarẹ Tinubu ati Oloye Bode George

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Alaga tẹlẹri fun ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), Oloye Bode George ti tun gbe ọrọ mii sita lori ipa ti ẹka idajọ n ko ninu ṣiṣe ipinu awọn to jawe olubori ninu eto idibo ni Naijiria.

Eyi n waye gẹgẹ bo ti n gba awọn ẹka idajọ nimọran pe ki wọn ma lo ẹtọ awọn eniyan lati maa ṣepinu ẹni to jawe olubori.

Bode George n sọ ọrọ yii lasiko ipade oniroyin to ṣe ni ile rẹ to wa ni Ikoyi lọjọ Aje lẹyin ti ile ẹjọ to n gbọ ẹsun nipa eto idibo ni Abuja kede pe wọn yoo ṣe idajọ ni Ọjọru.

Ninu atẹjade kan to jade latọwọ ile ẹjọ naa lọjọ Aje ni wọn ti kede pe Ọjọru ni awọn yoo ṣe idajọ lori awọn ẹsun to n pe aṣeyọri Bola Tinubu nija gẹgẹ bi ajaweolubori nibi idibo aarẹ ọdun 2023 eyi to wa latọdọ ajọ eleto idibo.

Ẹwẹ, nigba ti Oloye Bode n sọrọ nibi ipade to ṣe pẹlu awọn oniroyin, o ni kilode ti ẹka idajọ n ṣe ikede lati sọ ẹni to jawe olubori ninu eto idibo dipo ki ajọ eleto idibo tun eto idibo mii ṣe lati ṣe ọna abayọ fun nini awọn to jawe olubori gangan lootọ.

O ni: “Nnkan ti orilẹede wa ti n ṣe to tọ kere jọjọ nigba ti eyi ti ko dara ti pọ ju. Lati bi ọjọ diẹ sẹyin ni mo ti n ronu gẹgẹ bi ologun tẹlẹri ati gẹgẹ bi araalu ti mo ti ṣiṣẹ fun aarẹ marun.

“Ilana eto idibo wa ri rudurudu, ko si ọpọlọ ninu rẹ"

Oloye Bode George fi kun un pe: “Ilana eto idibo wa ri rudurudu, ko si ọpọlọ ninu rẹ bẹẹ si ni o n jẹ ki orilẹede yii lọ sibi iparun. Fifi eru ṣejọba lo fa a.”

Bode George tun tẹsiwaju pe aṣiṣe kekere lọjọ idibo jẹ ohun ti ko yẹ ko gba idariji tabi keeyan fi oju fo da “ṣugbọn alaga ajọ eleto idibo sọ fun wa pe awọn ti ṣetan fun idibo amọ pẹlu ohun to ṣẹlẹ, ọpọlọpọ iran to n bọ wa ko lee dari ji i.

“Ọrọ to n da wahala silẹ ju ni Naijiria ni ọrọ ẹka eto idajọ, o jẹ ọkan lara opo ijọba. Ṣe o wa tọ ki ẹka eto idajọ maa sọ ẹni to bori tabi ja kulẹ ninu idibo fun wa?

Ohun taa mọ nipa ijọba awa ara wa ni ijọba awọn araalu, latọwọ araalu ati fun awọn araalu ṣugbọn ni ti wa, ko yẹ ko jẹ ijọba ẹka ofin latọwọ ẹka ofin ati fun awọn to wa lẹka ofin. Ṣe ijọba tiwa n tiwa niyẹn?”.

Oloye Bode George tun ni ifẹ awọn eniyan lo yẹ ko bori. Bi ẹ ba kẹfin ohunkohun to lodi si ohun to yẹ, ẹ sọ fun wọn ki wọn pada ṣe eto idibo miran koda bi yoo gba wọn ni igba ọgọrun.

Bakan naa lo ni “iṣẹ awọn to wa ni ẹka ofin kii ṣe lati sọ ẹni to jawe olubori tabi ẹni to fidi rẹmi fun wa.”

Ẹnikẹ́ni tó bá ta félefèle lẹ́yìn ìdájọ́ ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ awuyewuye ìbò Ààrẹ yóò rugi oyin – iléeṣẹ́ ọmọ ogun, ọlọ́pàá

Nigeria Police

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ṣaaju idajọ igbimọ to n gbọ awuyewuye ibo Aarẹ Naijiria niluu Abuja lọla Ọjọru, ileeṣẹ ọlọpaa ati ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria ti sọ pe awọn yoo fi imu ẹnikẹni to ba da ilu ru lẹyin idajọ naa danrin.

Agbẹnusọ ileẹṣẹ ọmọ ogun, Brig. Gen. Tukur Gusau lo kilọ bẹẹ fun awọn to ba n pero wahala lẹyin idajọ naa ki wọn tu ero wọn pa.

Ọjọ aje ni igbimọ ọhun kede pe oun yoo gbe idajọ oun kalẹ lọjọru lori igbẹjọ to tako bi ajọ eleto idibo, INEC, ṣe kede Bola Tinubu gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori ninu ibo Aarẹ ọdun 2023.

Ọjọ kinni, oṣu Kẹta, ọdun 2023 yii ni alaga INEC, Mahmood Yakubu, kede pe Bola Tinubu lo jawe olubori ninu eto idibo naa, to si fidi Atiku Abubakar ati Peter Obi janlẹ.

Awọn adajọ ti yoo gbe idajọ naa kalẹ lọla ode yii ni alaga igbimọ ọhun, Haruna Tsammani; to fi mọ adajọ Stephen Adah, adajọ Monsurat Bolaji-Yusuf, Moses Ugo ati adajọ Abba Mohammed.

Awọn adajọ naa jẹ adajọ nile ẹjọ kọtẹmilọrun niluu Asaba, Kano ati Ibadan.

Ninu ibo Aarẹ naa ni Bola Tinubu ti ni ibo 8.9 miliọnu, Atiku Abubakar ni ibo 6.9 miliọnu, nigba ti Peter Obi ni ibo 6.1 miliọnu, ti awọn oludije marundinlogun mii si n tẹlẹ wọn lẹyin.

Ẹwẹ, marun un ninu awọn ẹgbẹ oṣelu mejidinlogun to dije lo lọ sile ẹjọ pe esi ibo naa ko ṣe itẹwọgba fun awọn.

Ejọ ti Atiku pe

Atiku ni ki ile ẹjọ wọgile esi ibo to gbe Tinubu wọle gẹgẹ bii Aarẹ, ki INEC si ṣ eto idibo tuntun miran.

Atiku tun sọ pe ki INEC gba iwe ẹri moyege ọwọ Tinubu nitori o lodi si ofin eto idibo Naijiria bi wọn ṣe fun Tinubu ni iwe ẹri ọhun.

Nigba tii yoo fesi pada, agbẹjọro Tinubu, Oloye Wole Olanipekun, SAN, sọ fun ile ẹjọ naa pe ẹjọ Atiku ko lẹsẹ nilẹ, nitori gbogbo igba lo maa n lulẹ ninu ibo Aarẹ Naijiria.

Amọ ṣa, lẹyin ti igbẹjọ naa bẹrẹ ni igbimọ to n gbọ ẹjọ ọhun wọgile ẹjọ ti ẹgbẹ AA ati APP pe, lẹyin ti wọn ni awọn ko ṣe ẹjọ mọ.

Ẹjọ ti Peter Obi pe

Ni ti Peter Obi, o ni ọpọlọpọ kudiẹkudiẹ lo waye lasiko ibo naa, ati pe igbakeji Tinubu, iyẹn Kashim Shettima ko tọ lati du ipo igbakeji Aarẹ nitori oun kan naa lo n du ipo Sẹnetọ.

O tun sọ pe Tinubu kuna lati bori ida to pọ ju ninu ibo naa, ati pe ko bori ida kan ninu ida mẹrin gbogbo igbo ti wọn di ni ilu Abuja.

Pupọ ninu awọn ‘Obidients’ ti wọn jẹ ololufẹ ati alatilẹyin Peter Obi lo gbagbọ pe iroyin ayọ ni idajọ igbimọ naa yoo jẹ fun awọn.

Ṣugbọn Aarẹ Bola Tinubu ti sọ pe oun ko mikan lori idajọ naa rara nitori ayọ ni yoo jẹ fun oun.

Ẹwẹ, igbimọ oludajọ naa ti sọ pe kedere ni gbogbo aye yoo wo idajọ naa lori ẹrọ amohunmaworan ati lori ayelujara lọla Ọjọbọ.

Ẹ̀rù kò bodò! Tinubu kò fòyà rárá lórí ìdájọ́ ìbò ààrẹ - iléeṣẹ́ ààrẹ

Aworan Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Babajide Sanwo-Olu/Twitter

Ile ẹjọ kọtẹmilọrun to n gbẹjọ awuyewuye to suyọ ninu ibo aarẹ orilẹede Naijria eleyii ti Bola Tinubu ti jawe olubori, ti kede pe oun yoo da ẹjọ ti ẹgbẹ oṣelu LP, PDP, APM, APP ati AA pe ajọ eleto idibo INEC pe Tinubu to jẹ oludije APC ko wọlẹ ibo naa ni Ọjọru.

Akọwe ileẹjọ naa, Umar M. Bangari lo fidi ọrọ yii mulẹ ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Aje.

O ṣalaye ninu atẹjade naa pe awọn eeyan yoo lanfaani lati wo eto igbẹjọ ọhun lori ẹrọ amohunmaworan ki gbogbo ọmọ Naijiria tẹ le igbẹjọ naa ni ṣisẹ n tẹle.

Ọgbẹni Bangari ṣalaye ninu atẹjade naa pe awọn ti wọn ba ti forukọ silẹ nikan ni yoo lanfaani lati wọ ile ẹjọ l’Ọjọru.

Bakan naa lo tun ṣalaye pe awọn agbẹjọro to fi mọ awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu na gbọdọ fi orukọ silẹ ki wọn to wọ ile ẹjọ.

Akọwe ile ẹjọ kotẹmilọrun wa rọ awọn araalu lati wo idajọ naa lori ẹrọ amohunmaworan wọn.

Ọgbẹni Bangari wa beere fun ifọwọsowọpọ awọn ọmọ Naijiria pẹli ileẹjọ ki igbẹjọ naa le kẹsẹ jari.

Ki ni Tinubu sọ lori idajọ to n bọ?

Ileeṣẹ aarẹ ti sọ pe Tinubu o mikan rara lori idajọ ti yoo waye ni Ọjọru niluu Abuja.

Oludamọran pataki si aarẹ lori ọrọ iroyin ati ilukoro, Ajuri Ngelale lo sọrọ yii lori ẹrọ amohunmaworan Channels Tv lọjọ Aje.

Ngelale ni Tinubu o foya nitori o wọle ibo aarẹ eleyii ti Atiku Abubakar to jẹ oludije ẹgbẹ PDP ati Peter Obi ti i ṣe oludije LP pe e lẹjọ si pe ko wọle.

Ẹwẹ, Tinubu gan an ko ni si ni Naijiria nigba ti idajọ naa yoo maa waye.

Ọjọ Aje ni aarẹ Naijiria rinrin ajo lọ si orilẹede India fun apero awọn orilẹede G-20.

Ọjọ kinni oṣu Kẹta ọdun 2023 yii ni ajọ INEC kede pe Tinubu lo jawe olubori ninu ibo aarẹ orilẹede Naijiria.

Ajọ INEC ni ibo 8,794,726 ni Tinubu ri nigba ti Atiku ẹgbẹ PDP to ṣe ipo keji ri ibo 6,984,520, bakan naa ni Obi ti LP lo ṣe ipo kẹta pẹlu ibo 6,101,533.