Wo àkóbá tí àdínkù súnkẹrẹ fàkẹrẹ ṣe nílùú Eko lẹ́yìn yíyọ owó ìrànwọ́ epo

Aworan ọkọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ wa lara awọn abudu ipinlẹ Eko lati ọjọ to ti pẹ.

Ṣugbọn ti ẹ ba ṣe akiyesi daadaa, o dabi ẹni pe sunkẹrẹ fakẹrẹ ti poora loju popo nilu Eko lati igba ti ijọba Aarẹ Bola Tinubu ti yọ iranwọ owo ori epo kuro eleyii to mu ki owo epo bẹntiroolu di gọbọi.

Kete ti owo epo bẹntiroolu lọ soke lati ibẹrẹ oṣu kẹfa ni ọwọ ọkọ naa ti wọn sii eyi to jẹ ki ọpọ oṣiṣẹ maa ṣiṣẹ lati ile.

Ọpọ onimọto aladani lo ti gbe ọkọ wọn sile tori owo epo to ti di ilọpo mẹta.

Koda ọpọ awọn bọọsi ero ni ko ri ero gbe mọ bi ti tẹlẹ.

Eleyi gan an lo jẹ ki sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ dinku gam am loju popo niluu Eko.

Ilu Eko ti eeyan to le ogun miliọnu n gbe ti wa n pa lọlọ diẹdiẹ bayii tori awọn to n gbe ọkọ jade ko pọ mọ.

Bọọsi elero ni Eko

Ipalara wo ni aisi sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ mọ le fa fun ilu Eko?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Aisi sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ mọ niluu Eko ti sẹ akoba fun eto ọrọ-aje olu ilu orilẹede Naijiria tẹlẹ ri.

Owo epo to wọn ati owo naira ti ko gbewọn to mọ lati igba ti ti Tinubu kede iyọkuro iranwo owo ori epo ti jẹ ọpọ ileeṣẹ kogba sile.

Koda ọpọ eeyan ti owo oṣu wọn ko to nkan ti wọn n ṣiṣẹ niluu Eko ṣugbọn ti wọn n gbe lagbegbe ilu naa ni ko le lọ sibi iṣẹ mọ nitori owo ọkọ to pọ.

Gẹgẹ bi akọsilẹ ajọ National Bureau of Statistics, ipa ti ẹka igbokegbodo ọkọ ninu ọrọ-aje ti dinku pẹlu ida mẹtadinlaadọta lọdun 2023 ti a bo wo si ọdun 2022.

Bakan naa ni akọsilẹ fihan pe ọpọ oṣiṣẹ lo ti padanu iṣẹ lati igba ti ijọba ti yọ iranwo owo epo kuro.

Awọn oṣiṣẹ miiran ti wọn si wa lẹnu iṣẹ ko le wọ ọkọ mọ, kẹkẹ ni wọn n gun lọ sibi iṣẹ bayii.

Awọn eeyan kan ti ṣe ifẹhonuhan kaakiri lori bi ilu ṣe le kankan lẹyin ti ijọba owo iranwọ ori epo, amọ, ifẹhonuhan naa ko fẹsẹ mulẹ.

Awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ naa ṣe ifẹhonuhan diẹ, ṣugbọn ko kẹsẹ jari.

Ju gbogbo rẹ lọ, ọwọn epo ti mu adinku ba sankẹrẹ fakẹrẹ ati ero giri giri niluu Eko.