Ẹ má sọdá lójú ọ̀nà Reluwé Blue Rail, iná mọ̀nàmọ́ná wà lára rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Ijọba ipinlẹ Eko
Ijọba ipinlẹ Eko ti ṣe ikilọ fun araalu lati ma ṣe sọda loju ọna rulewe Blue Rail Line ti yo bẹrẹ isẹ lọjọ Aje.
Ijọba gbe ikilọ yii jade lati ẹnu agbẹnusọ Gomina Iipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, Gboyega Akosile rọ awọn araalu lati lo afara ti ijọba pese lasiko ti wọn ba sọda nitori ina mọnamọna wa loju ọna Reluwe naa.
“Ẹyin ipinlẹ Eko, bi Reluwe Blue Line Rail ṣe n bẹrẹ lọla yii, a fẹ ki ẹ mọ pe ina wa loju ọna reluwe naa.
“Ẹ ma ṣe sọda loju ọna naa nitori pe o le wu pupọ. Ẹ lo afara ti ijọba pese fun yin lati fi sọda.”
Bakan naa, alakoso eto irina ipinlẹ Eko, Abimbola Akinajo, ninu fọnran kan to gbe sita ni kọminu lori bi awọn eeyan kan ṣe gbe afara sori ọna reluwe naa lati fi sọda.
“Pẹlu Reluwe Blue Rail ṣe n bẹrẹ isẹ lọla, a fẹ ki ẹ mọ pe ina mọnamọna to gbe eeyan wa lara ọna reluwe naa.
“Ijọba ti pese afara fun yin lati fi sọda, bakan naa ni a fese abo fun ọna naa lati ri pe awọn eeyan ko sọda loju ọna naa sugbọn o ya wa lẹnu bi awọn ṣe ba awọn abo ti a pese sibẹ nitori wọn fẹ sọda.
“A n bẹ awọn eeyan lati bọ wọ fun asẹ yii nitori ti a ba kọ lati tẹle, o lewu pupọ.”















